Ọ̀kùnrin ọdún 75 gbẹ́mìí mì nínú odò Ọ̀sà l'Eko

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'A jọ wà nínú ọkọ̀ kan náà ni kó tó bọ́ọ́'lẹ̀'

Arákùnrin kan tí òun àtàwọ́n akẹ́gbẹ́ rẹ̀ jọ ń lọ sí ibi iṣẹ́ ti ṣàà dédé kó sínú odò ọ̀sà látoríi afárá Third Mainland ní ìpínlẹ̀ Eko.

Ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú akọ̀ròyìn BBC níbi tí àwọn tó kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú arákùnrin náà ti ń sọ ohun tí ojú wọn rí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

PDP kó Tinubu ní ìjánu lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí Atiku

‘Afẹnifẹre lé Sẹnetọ Omisore nítorí kò finú hàn wọ́n’

Àkọlé àwòrán Etí odò Ọ̀sà
Àkọlé àwòrán Etí odò Ọ̀sà

Ọgbẹ́ni Yemisi Nubi, ẹni tó wa ọkọ̀ ọ̀hun ṣàlàyé wí pé gbogbo àwọn tó wà nínú ọkọ̀ náà jọ ń sọ̀rọ̀ ni kí arákùnrin ọ̀hún tó bẹ́ sínú omi.

Nígbà tí BBC Yorùbá kàn sí àjọ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko (LASEMA), agbẹnusọ àjọ náà, Kehinde Adebayọ jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn òṣìṣẹ́ adóòlà gbìyànjú láti yọ ọ́ jáde láàyè.

Ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo ìgbìyànjú wọn, arákùnrin náà rékọjá sí ọ̀run alákeji.

Àkọlé àwòrán odò Ọ̀sà

Akọ̀ròyìn BBC tó wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún jẹ́ kó di mímọ̀ pé

A ó máa mú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn náà wá fún yín bó bá ṣe ń lọ.