Aláboyún: Fọ́tò ọmọ ìyá mẹ́ta tí wọ́n lóyún lu ayélujára pa

Chika Okafor, Ogechi Babalola ati Onyeka Ufere
Àkọlé àwòrán,

Àńkò oyún ọmọ ìyá mẹ́ta

Ankoo aṣọ wiwọ la saba maa n ri laarin awọn eniyan.

Sugbọn oriṣiriṣi ara lawọn eeyan n da nisinyi, eyi lo difa fun awọn ọmọbinrin mẹta yii Chika Okafor, Ogechi Babalola ati Onyeka Ufere ti wọn ko anko oyun.

Koda fọto awọn mẹtẹẹta nibi ti wọn ti n rẹrin pẹlu oyun ninu wọn ti lu oju opo ayelujara pa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Kí ló lè mú aláboyún kábamọ̀ lásìkò ìrọbí?

Ọmọ orilẹede Naijiria ni awọn obinrin mẹtẹẹta yii, ṣugbọn ilẹ Amẹrika ni wọn fi ṣe ibugbe bayii.

Ẹgbọn patapata laarin awọn mẹtẹẹta Onyeka ni ẹni akọkọ ninu fọto wọn ti Chika si wa laarin nigba ti Ogechi ti o kere julọ ninu wọn duro sapa ọtun.

Ohun to yani lẹnu ni pe asiko kan naa lawọn mẹtẹẹta loyun si.