Ìwà olè, jìbìtì àti ìjẹkújẹ ló n jé káwọn mii yí ọjọ́ orí wọn padà

Ìwà olè, jìbìtì àti ìjẹkújẹ ló n jé káwọn mii yí ọjọ́ orí wọn padà

Ọpọlọpọ gbàgbọ́ pé nitori pé kò sí iṣẹ́ nigboro ni àwọn kan ṣe n parọ́ ọjọ́ orí wọn.

Àwọn mii gba pe ko yẹ ko ri bẹẹ, ati pe o yẹ kijọba tete gbe ofin sita to maa tako fifi ofin de ọjọ ori awọn to péye to yẹ ko gba iṣẹ ti wọn ba ti kunju oṣuwọn tó.

Awọn miran ti BBC Yoruba fọrọ wa lẹnu wo naa mẹnuba iṣoro to n koju akẹkọọ ni Naijiria bii iyanṣẹlodi awọn olukọ ati bẹẹ bẹẹ lọ ni eyi ti kii jẹ ki akẹkọọ pari ẹkọ rẹ lasiko.

Ero awọn mii ni pe, òpùrọ́ ni àwọn onile iṣẹ to n fi gbedeke ọjọ ori gba oṣiṣẹ nitori pe wọn ko lowo lati san fawọn to kunju oṣuwọn ni.

Wọn rọ ijọba lati tete pari igbese lori mimu ofin naa ṣẹ pe ki ẹnikẹni to ba ti kunju oṣuwọn gba iṣẹ to ba ni iriri fun.