''Oúnjẹ òkèlè le ṣàkóbá fún ara''
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ètò ìlera: Òróró àti oúnjẹ òkèlè púpọ̀ jù le fa ẹ̀jẹ̀ rúru àti àrùn rọpárọsẹ̀

Ilera loogun ọrọ. Onimọ nipa ere idaraya ati imu-ara-ji-pipe, Ṣeyi Oluṣore, ṣalaye pe ọpọ ounjẹ lo n ṣakoba fun agọ ara eniyan.

O salaye pe jijẹ awọn ounjẹ bii okele lasiko ti ko yẹ pẹlu ororo le mu ki eeyan ni arun rọparọsẹ, koda o tun le fa ẹjẹ ruru fun eniyan.

Ọgbẹni Oluṣore sọ pe o ṣe pataki lati kọkọ mu omi ti eeyan ba kọkọ ji laarọ ko o to ṣe ohunkohun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun ọrọ rẹ pe eeyan gbọdọ maa sun fun wakati mẹjọ, ati wi pe o tun ṣe pataki lati maa ṣe ere idaraya ki ara le maa ji pepe.

O tun sọ pe awọn nkan dundun bi shawarma ati oriṣiriṣi ipapanu ti wọn n ta nile ounjẹ igbalode le ṣakoba fun ara.

Alakoso Shedams naa sọrọ lori àwọn nkan marun un to lewu jù to yẹ ki eeyan sá fún lasiko yii.

O gba awọn eeyan nimọran lati sá fún ṣúgà jijẹ yala ninu ẹlẹrin dodo tabi ninu ounjẹ.

O ni ki àwọn ẹni to ba n fẹ ilera to yè koro ma joko soju kan, ki wọn maa rin kaakiri paapaa awọn to n ṣiṣẹ ijoko.

Ni ipari, akọṣẹmọṣẹ lori eto ilera yii, ṣalaye pataki jijẹ èso nigba gbogbo fun BBC Yorùbá pé o maa n jẹ ki ọpọlọ ji pipe ki ara wa ni ilera ni.