Ṣé o fẹ́ mọ òdiwọ̀n iṣẹ́ oòjọ́ àwọn òṣìṣẹ́ rẹ?
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Tony Elemelu Foundation: Gbogbo okòwò ló ní ìdojúkọ!

Mahason Quadri wá ojútùú si ọ̀kan lára àwọn ìṣoro oniṣowo nipasẹ ẹ̀rọ igbalode lilo.

Mahason lo pegede ninu idije to ṣagbeyẹwo irọri ọrọ̀ ajé to lamilaaka ninu idije ọlọdọọdun ti ajọ aranilọwọ ti kii ṣe tijọba, Tony Elemelu Foundation maa n ṣe fawọn ọ̀dọ́ ilẹ Afrika.

O ṣalaye ohun to ṣokunfa iṣẹ iwadii rẹ ati awọn igbesẹ ti oun gbe lati fi ṣe ẹrọ igbalode fawọn ontaja lasiko yii.

Ẹrọ igbalode ti Mahason ṣe fi gbegba oroke idije ẹgbẹrun lọna aadọta owó dọla ilẹ okeere to jẹ $50, 000 ni ẹnikẹni le fi sori ẹrọ ibanisọrọ rẹ̀.

Ẹrọ yii yoo fun ontaja laaye lati mọ odiwọn iye iṣẹ ti àwọn oṣiṣẹ rẹ n ṣe lojumọ, yoo jẹ ki o mọ iye ọja ti o tà, iye èrè ti o jẹ, tabi iye gbèsè to ku nilẹ kódà koo ma si nibi okòwò rẹ.

Mahason ṣalaye lori igbesẹ to gbe ki ajọ Tony Elemelu to fun oun owó iranwọ akọkọ to fi ṣe igbesoke ẹrọ naa dadaa.

Ma jẹ ki ohunkohun dènà ìran àti àlá rẹ nitori igbesẹ kan péré ló n sọ eniyan di olokiki.

Related Topics