#Oshiomole: Àwọn aṣáájú APC kò mọ ohun ti wọ́n n ṣe lásìkò yí

#Oshiomole: Àwọn aṣáájú APC kò mọ ohun ti wọ́n n ṣe lásìkò yí

O ni àwọn aṣáájú APC kò lé ri ìyọ́nú àwọn ènìyàn Kwara ti wọn kò bá ṣe àtúnṣe tó yẹ.

Ọjọgbọn Shuaib Abdularaheem Ọba to jẹ olukọni fasiti Ilọrin ati ọga agba pata nibẹ fun ọpọlọpọ ọdun sẹyin ba BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ lórí nkan to n ṣẹlẹ lọ́wọ́ ni ẹgbẹ́ oṣelu APC nipinlẹ Kwara bayii.

O mẹnuba àwọn kudiẹ-kudiẹ ti oun woye pẹlu ọna ti awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC ṣe n ṣejọba ara wọn lasiko yii.

O fẹsun kan awọn adari ẹgbẹ naa pé wọn ti gba ifẹ́ owó lati jọba lọkan wọn ni eyi ti kò le mu idagabsoke to yẹ ba ẹgbẹ.

Ọjọgbọn Ọba fi aidunnu rẹ̀ hàn lori eto idibo abẹnu to waye ni Kwara lati yan oludije pé ko dara to.

O ni ọ̀rọ̀ Oshiomọle dabi afiwe Ọba to jẹ tilu tòòrò ati eyi to jẹ ti ilu túká ni, orukọ wọn kò ni parẹ ninu iwe ìtàn.

O ni ki gbogbo awọn aṣoju ẹgbẹ APC lọ tun èrò wọn pa, ki Oshiomọlẹ ranti pe orukọ rere sàn ju wura ati fadaka lọ.

Ni ipari, o sọrọ nipa iriri rẹ nigba to ṣẹṣẹ bẹrẹ oṣelu lẹgbẹ PDP ko to lọ si APC.