Akinọla: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀

Akinọla: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀

Ìfipá-bọmọdélòpọ̀ jẹ́ ohun tí òbí gbudọ̀ sàkíyèsí

Òbí gbọ́dọ̀ ṣe ìwádìí ní kíkùn lóri ibikíbi ti ọmọ bá ń lọ.

BBC Yorùbá fọ̀rọ̀ wa Olootu Parental Guidance and counselling, Akinọla Akinrọpo lẹnu wo lori ọna abayọ siṣoro ifipaba-ọmọde-lopọ to n ṣẹlẹ lẹraléra lasiko yii.

Ogbẹni Akinrọpo sọrọ nipa iriri rẹ pé ki òbí má nigbagbọ pé ẹnikan kò le ṣe ọmọ wọn nibi nitori pe ayé ti dorikodo, àṣà ti n sọnu.

O ni asiko iwadii kikun ni òbí wa bayii lori ohunkohun ti ọmọ ba sọ fun òbí nipa ẹnikẹni.

Onímọ̀ nípa iṣẹ́ òbi ati itọju ọmọ yii ṣalaye awọn nkan to yẹ ki obi woye ti wọn lè fi mọ ti ọmọ wọn ba wà ninu ewu kankan.

O ni ki òbí wo fun ọmọ to n ṣere tẹlẹ to wa deede n dakẹ ninu ilé, ọmọ tinu rẹ kò dùn mọ.

Ọmọ to n ri ẹ̀bí, ará, ọ̀rẹ́ yin tabi iyekan yin kan to n sá tabi to n farapamọ.

Ni ipari, akọṣẹmọṣẹ yii rọ àwọn obi lati maa farabalẹ gbọ ọrọ ẹnu ọmọ wọn ki wọn si maa ṣe iwadii to yẹ lori ohun ti ọmọ ba sọ fun wọn nitori ẹ̀ṣẹ́ kìí deede ṣẹ́.

O ni ki obi dẹkun fifi agidi mu ọmọ lọ lo isinmi nibi ti ko fẹ tabi lọ ki ẹnikẹni nile ti ọmọ naa kò fẹ

Ọpọlọpọ iṣẹlẹ lo ti han de lori bi àwọn ẹ̀bí atawọn aladugbo ṣe n ṣe awọn ọmọde niṣekuṣe lasiko yii ni eyi to tó àpérò ọmọ eríwo.

#parental guidance