Aremu Afolayan: Kí ni oun tí mo sọ tí kò dáa?
Aremu Afolayan: Kí ni oun tí mo sọ tí kò dáa?
Láìpẹ́ yìí ni gbajúgbajà òṣèré tíátà Kunle Afolayan fi síta lójú òpó Twitter rẹ̀ wí pé òun kọ́ ni àwọ́n ènìyàn rí nínú fọ́nrán kan tí wọ́n ti ní òun sọ ọ̀rọ̀ òdì sí Ààrẹ Buhari àti ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú Ethiopia.
Kunle Afolayan ní ṣe ni òun ń gba ìpé látọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn káàkiri lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ àti ẹ̀rọ ayélujára wí pé òun làwọn rí.
Ẹ̀wẹ̀, Aremu Afolayan tó jẹ́ abùrò rẹ́ tóun náà sí jẹ́ gbajúgbajà òṣèré tíátà gangan ni ó ṣe fọ̀nrán ọ̀hún síta. Aremu ní òun ò kó ọ̀rọ̀ òun jẹ́ wí pé, bí òun ṣe sọ ọ́ bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ló rí.
Àmọ́ ṣá, ó ní "Kúnle Afolayan sẹ́ mi, sùgbọ́n èmi kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ sí i.