Sickle cell: dókítà kìlọ̀ f'áwọn ọ̀dọ́ lórí ẹ̀jẹ̀ AS

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

Ààrùn arunmọléegun ti lóògùn ti wà báyìí

Dokita Michael kilọ pe ọkunrin ti ẹjẹ rẹ bajẹ ''AS'' ko ma ṣe fẹ obinrin ti ẹjẹ tiẹ naa ba jẹ ''AS'', bibẹẹkọ o ṣeeṣe ki wọn bi ọmọ ti yoo larun arunmọleegun.

O ṣalaye pe ẹni kẹni to ba larun yii gbọdọ maa ri dokita loorekoore fun itọju, bẹẹ wọn gbọdọ maa mu omi nigba gbogbo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Oogun ti wa fun aarun sickle cell

O gba awọn obi to ti bi ọmọ to ni arun yii lati maa gbee lọ sile iwosan loorekoore, ki wọn maa fun un ni omi mu daadaa bẹẹ ko gbọdọ wa ninu otutu jù.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Àkọlé fídíò,

Ìran kan si ìkejì ló n gbèrò láti ṣe ìrú ìgbéyàwo àjùmọ̀ṣe 'Shao' fọ́mọ wọn

Ṣugbọn o fi kun ọrọ rẹ pe aarun arunmọleegun ti ni oogun bayii.

Dokita Michael ni iṣẹ abẹ ọra inu egungun ni oogun aarun arunmọleegun bayii, ṣugbọn ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu naira ni wọn fi n ṣe.

Ẹ wo ǹkan mẹ́ta tí àwọn ènìyàn fi n sàférí Tosyn Bucknor

Awọn ẹbi, ara ati ọrẹ pẹlu ojulumọ Tosyn Bucknor sọrọ iwuri nipa igbe aye rẹ gẹgẹbi ọmọluwabi ni gbogbo ọna.

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán,

Òsìsẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ pẹ̀lú ilé isẹ́ Inspiration FM, Tosin Bucknor ti jáde láyé lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínlógójì.

Eyi ni awọn nkan mẹta ti ọpọlọpọ fi maa ṣafẹri Tosyn ti won ma n pe ni 'area mama' nigboro.

Ọna ìmúra rẹ̀

Oloogbe yii ma n mura bi ọkunrin ni lọpọ igba ni eyi ti awọn kan maa fi n pe ni Sisi Eko.

Ajanaku kọja mo ri nkan firi ni, ko si ẹni to pade Tosyn ti ko mọ pe oun pade eeyan kan.

Agbára rẹ̀ lẹnu iṣẹ

Tosyn Bucknor kii ṣe ọlẹ lẹnu iṣẹ sọrọsọrọ rara. Ko si ẹni to maa forowalẹnuwo nileeṣe agbohunsafẹfẹ ti ko ni mọ pe oun laagun nitori pe o maa sọju abẹ niko ni.

Ọpọ awọn to ti baa ṣiṣẹ ni wọn ni o maa n le wọn lere lati kọ sii nipa iṣe igbohun safẹfẹ nitori pe o maa n dabi pe ẹ ti mọ ara yin ti pẹ ni ti o ba kọkọ pade rẹ.

Awọn ololufẹ ẹ ni ti ẹ ba n gbọ ọ lori ẹrọ asọrọmagbesi, niṣe lo maa n dabi pé, Tosyn wa lẹgbẹ yin ni.

Ile ise Inspiration FM toloogbe ti ṣiṣẹ gbeyin ni àwọn yoo yi eto wọn pada loni, ọjọ iṣegun lati fi bu ọla fun Tosyn Bucknor.

Onkọrin ni Area Mama

Tosyn Buckner jẹ akorin takasufe to ti gbe awo orin sita sẹyin.

Ọpọlọpọ awọn ololufẹ orin onijo lo fẹran orin ọmọ Bucknor ti gbogbo eeyan mọ si area.

Titi Oyinsan to jẹ ọrẹ Tosyn Bucknor bá BBc sọrọ lori Area Mama pe:

Àkọlé fídíò,

Titi Oyinsan:Tosyn Bucknor kun fun ayo, okun ati agbara

Naijiria ṣọ̀fọ̀ Tosyn Bucknor

Ọpọlọpọ eniyan lo ti n sọrọ rere nipa gbajugbaja oniroyin ati osisẹ pẹlu ile isẹ igbohunsafẹfẹ Inspiration FM, Tosyn Bucknor ti jade laye lẹni ọdun mẹtadinlogoji.

Iroyin sọ pe ọkọ rẹ, Aurelien Boyer lo ba oku rẹ nilẹ, lẹyin ti o ti ibi isẹ de ni alẹ Ọjọ Aje.

Funkẹ Bucknor to jẹ ẹgbon oloogbe ni arun sickle cell to ti n baa finra naa lo pada gbẹmi Tosyn.

Azu Osumili to jẹ ọga rẹ ni 92.3 Inspiration FM ṣalaye fun BBC pe igba ti wọn fi maa gbe e de ile iwosan ni wọn fidi ẹ mulẹ pé o ti jade laye.

Falz, Yemi alade atawon oṣere miran n ṣelede lẹyin ẹni rere to lọ.

Ẹgbọn Tosyn, Funkẹ Bucknor náà sọrọ lori ibanujẹ ọkan rẹ lori iku gbajugba sọrọsọrọ naa pé:

Awọn ọrẹ ati ojulumọ ti o ti ba a sisẹ ni ile isẹ iroyin Top Radio ati awọn ololufẹ rẹ lori afẹfẹ n ba a kẹdun lori ẹrọ ikansiraẹni Twitter.

Àkọlé fídíò,

Ọmọge Campus, ó dàárọ̀ o

Tosyn Bucknor to kawe gboye onimọ nipa ofin lati Ile-Iwe Giga Fasiti Eko, ni wọn bi pẹlu aisan sickle cell anaemia.

Ki Ọlọrun dẹlẹ̀ fun ẹni rere tó lọ.