Ìran kan si ìkejì ló n gbèrò láti ṣe ìgbéyàwo àjùmọ̀ṣe 'Shao' fọ́mọ wọn

Ìran kan si ìkejì ló n gbèrò láti ṣe ìgbéyàwo àjùmọ̀ṣe 'Shao' fọ́mọ wọn

Gbogbo ìlú lọ máa sin iyawo ọ̀sìngín ni Shao ni Kwara lọ sile ọkọ tìlù tìfọn pẹlu ijo àti ayọ láìyọ yínyin ìbọn àwọn ọdẹ akọni sílẹ̀.

Àjọdun 'Àwọ́nga Shao' ni wọn n pe eto igbeyawo ajumọṣe yii ni ìlú Shao ni ipinlẹ Kwara ni eyi ti wọn maa n ṣe lọdọọdun lati fi sin ọpọlọpọ ọmọbinrin wọn lọ sile ọkọ lọjọ kan naa.

Reuben Akano to jẹ adari eto tọdun 2018 ṣalaye kikun nipa igbeyawo yii fun BBC Yoruba àti pataki diduro gba adura òbí ati ti gbogbo ìlú lọjọ naa lapapọ.

Iya afin Ibirọgba, ọkan lara awọn oloriirie to n fa ọmọ fọko ṣalaye fun BBC Yoruba lori igbesẹ inu eto igbeyawo ajumọṣe ti Shao yii tayọtayọ.

Hajarat Ajao, to jẹ ọkan lara awọn iyawo ẹlẹsẹ osùn tọdun 2018 ni oun gbadura lati ṣe iru rẹ fọmọ oun naa.

Adewale Tẹniọla, ọkan lara àwọn ọkọ iyawo ni ìmúra iyawo lapapọ ati bi gbogbo èrò ṣe maa n wọ tẹle wọn léyin lo maa n dun mọ oun.

Sarah Oladunni, to jẹ adari eto fun tọdun yii ni awọn iyawo mẹẹdọgbọn ni ìlú n fà fọkọ nigba ti todun to kọja jẹ aadọta.

Awọn agbatẹru eto naa ni ọ̀làjú ati ẹ̀sìn igbagbọ ati musulumi ti n mu ẹ̀dínkù ba iye awọn to n kopa ninu igbeyawo ajumọṣe naa bayii.

Gbagede ilu ni wọn a ti pari eto naa pẹlu adura ati imọran loriṣiiriṣi fun tọkọtaya lati ẹnu gbogbo ìlú.