Ààrùn arunmọléegun ti lóògùn
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ààrùn arunmọléegun ti lóògùn ti wà báyìí

Bi ọgọrọ eeyan ti ṣe idaro gbajugbaja agbohunsafẹfẹ to papoda Tosyn Bucknor, bẹẹni dokita kan Gbala Michael to ba BBC Yoruba sọrọ n gba wọn ọdọ niyanju lati fẹ ẹni ti ẹjẹ wọn bara mu ki wọn le dena aarun arunmọleegun (sickle cell anaemia).

Dokita Michael kilọ pe ọkunrin ti ẹjẹ rẹ bajẹ ''AS'' ko maa ṣe fẹ obinrin ti ẹjẹ tiẹ naa bajẹ ''AS'', bibẹẹkọ o ṣeeṣe ki wọn bi ọmọ ti yoo larun arunmọleegun.

O ṣalaye pe ẹni kẹni to ba larun yii gbọdọ maa ri dokita loorekoore fun itọju, bẹẹ wọn gbọdọ maa mu omi nigba gbogbo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Ṣugbọn o fi kun ọrọ rẹ pe aarun arunmọleegun ti ni oogun bayii.

Dokita Michael ni iṣẹ abẹ ọra inu egungun ni oogun aarun arunmọleegun bayii, ṣugbọn ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu naira ni wọn fi n ṣe.