'Ẹ má fi ọmọ kẹ́ ọmọ mọ́, ìbí kò ju ìbí lọ'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

BBC 100 Women: Fanny gbà kádàrá lórí àwọn orin rẹ̀ kí wọn to ṣe alakọkọ lọdun 2012

Baba Fanny lo ti kọkọ n gbé ògo orin ọmọdebinrin Fanny fun Felix ẹgbọn rẹ lati kekere wọn.

Fanny Mendelssohn je ọmọbinrin ti baba rẹ fẹran ọmọ rẹ ọkunrin ju lọ ninu ilé.

O fẹran orin kikọ pupọ ṣugbọn baba rẹ máa n figba gbogbo sọ fun Fanny pe, ẹgbọn rẹ Felix lo máa kọ orin là.

Iyalẹnu lo je fun gbogbo eniyan pe orin Fanny lo pada gba ami ẹyẹ orin ti Ọbabinrin Victoria ti ilẹ Gẹẹsi fẹran jù nigba aye rẹ.

Lẹyin iku Fanny ni wọn ṣẹṣẹ bẹrẹ si ni gbe orin rẹ jade loriiṣiiriṣii.

Ọdún 2012 ni wọn kọkọ fi orin Fanny ṣe ere fun igba akọkọ lorukọ rẹ.

Ti obi ba n fi ọmọ kan kẹ ọmọ keji, wọn máa n pa irawọ mọ iru ọmọ beẹ lara ni.

#BBC100women

Related Topics