Piracy: Ohun tí ojú òǹkọ̀wé, olórin ń rí ni Jonathan àti Ọbasanjọ rí lórí ìwé wọn

Ile itawe kan
Àkọlé àwòrán,

Kaakiri agbaye ni ipenija jiji iṣẹ ọpọlọ ti n waye

Awọn onwoye ti ṣalaye pe ere aigbe igbesẹ ti o tọ lori awọn ole to n ji iṣẹ ọpọlọ ni awọn aarẹ tẹlẹ lorilẹede Naijiria n jẹ pẹlu iṣẹ ọpọlọ wọn ti awọn ole yii n ji.

Ọrọ awọn ole ti wọn n ji iṣẹ ọpọlọ elomiran ta ti di ipenija ọjọ pipẹ fun awọn oniṣẹ ọna, orin, onkọwe ati awọn iṣẹ ọpọlọ miran ni orilẹ-ede Naijiria.

Amọṣa, ṣe wọn ni aisan to ṣe ọmọ talaka ti wọn ni o tun ti gbe iṣe rẹ de, bo ba ṣe ọmọ olowo, wọn a ni ko rọju bu ata sẹnu.

Àkọlé àwòrán,

Goodluck Jonathan pariwo pe wọn ti ji iṣẹ ọpọlọ oun

Ariwo gee ta lori iwa yii pẹlu bi awọn olori orilẹ-ede Naijiria bii Oluṣẹgun Ọbasanjọ ati Goodluck Jonathan ṣe darapọ mọ awọn to pariwo jiji iṣẹ ọpọlọ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni ọjọ Aje ni aarẹ ana, Goodluck Jonathan ko iwe rẹ, My Transition hours jade. Ki ilẹ ọjọ keji to mọ ni ẹda rẹ ti gba ori ayelujara kan; to bẹẹ gẹẹ ti aarẹ ana naa fi ke ibosi sita pe ki araye gba oun.

Arabinrin Folukẹ Daramọla jẹ ọkan pataki lara awọn oṣere onitiata ati olorin lorilẹ-ede Naijiria ti o ti n polongo ki ijọba gbe igbesẹ lori ipenija naa ṣugbọn ti o ja si pabo.

Àkọlé àwòrán,

Awọn onwoye ti ṣalaye pe ere aigbe igbesẹ ti o tọ lori awọn ole to n ji iṣẹ ọpọlọ ni awọn aarẹ tẹlẹ lorilẹede Naijiria n jẹ

Ninu ọrọ ti o ba BBC News Yoruba sọ, o ni aiṣe ohun ti o tọ nipa iṣẹ ọpọlọ jiji wa lara akoba ti awọn oniṣẹ ọpọlọ n koju.

"Ọpọ awọn oniṣẹ ọpọlọ ni wọn ti pa ni apasaye nitori awọn to ti ji iṣẹ ọpọlọ wọn. A ti pariwo fun ijọba ṣugbọn boya nitori pe o ṣeeṣe ki awọn eeyan wọnyii ni awọn eeyan ni ibi giga, pabo ni ọrọ naa n jasi"

Ni tirẹ, akọwe agba fun ẹgbẹ awọn to n gbe iwe sita lorilẹ-ede Naijiria, Nigeria Publishers Association, Ọgbẹni Emmanuel Abimbọla ni awọn oniṣẹ ọpọlọ, paapaa awọn onkọwe ti gba fun Ọlọrun lori ipenija yii nitori gbogbo igbesẹ to yẹ ni gbigbe lati daabo bo iṣẹ ọpọlọ wọn ni wọn n gbe sibẹ pabo lo n ja si.

Àkọlé àwòrán,

Biliọnu meji dọla owo ilẹ Amẹrika ni orilẹede Naijiria n padanu lọdun lori ipenija awọn ole to n ji iṣẹ ọpọlọ

Ijọba ni lati ṣe iṣẹ nipa didaabo bo iṣẹ ọpọlọ. Awọn ofin ati ileeṣẹ ti ofin gbe kalẹ lori rẹ gbọdọ gba agbeyẹwo lati ba igba mu. Lọwọ yii n ṣe ni awọn oniṣẹ ọpọlọ n ṣiṣẹ bi erin ṣugbọn ti wọn n jẹ ijẹ ẹliri.

Nigba ti awọn mejeeji yii sọrọ lori ariwo ti aarẹ ana Goodluck Jonathan pa lori iwe rẹ ti wọn ji ta, wọn ni ogun jẹ lọ, ọgbọn jẹ bọ ni ọrọ naa.

Folukẹ Daramọla ni, "afaimọ ki wọn maa gbe awọn gan an lọ lodindi nitori kini wọn ṣe nigba ti a n pariwo rẹ si wọn leti lori oye?"

"Nigba ti a ba n ri ti wọn n ji iṣẹ aarẹ ta, a jẹ pe ina ti jo de ori koko niyi. Kii ṣe iṣẹ ọpọlọ Jonathan nikan ni wọn ji ta, koda wọn ji ti aarẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ naa ta pẹlu"

Ninu agbekalẹ kan, ọjọgbọn eto oṣelu ọrọ aje, Pat Utomi ni biliọnu meji dọla owo ilẹ Amẹrika ni orilẹede Naijiria n padanu lọdun lori ipenija awọn ole to n ji iṣẹ ọpọlọ wọnyii.