Wike: Kọngílá, onílé àti òṣìṣẹ́ ìjọba tó bá lọ́wọ́ nínú ilé alájà tó dàwó ní Portharcourt yóò fojú winá òfin

Wike n ṣe abẹwo si ile to wo Image copyright @GovWike
Àkọlé àwòrán Èèyàn méjìdínlọ́gbọ̀n ni wọ́n ti yọ láàyè lábẹ́ àwókù ilé alájà náà

Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ti paṣẹ ki awọn agbofinro mu kọngila ati ẹni to ni ile alaja meje to dawo ni ilu Portharcourt ni ọjọ ẹti.

Gomina Wike ni gbogbo awọn to lọwọ si kikọ ile naa ni wọn yoo fi jofin.

O kere tan ẹmi mẹfa lo ba iṣẹlẹ naa rin, ti awọn miiran si fi ara pa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Davido, Falz, Tiwa Savage tàn bí oòrùn ní AFRIMA

Atiku Abubakar di Waziri Adamawa lọ́jọ́ ìbí rẹ̀

"Ẹnikẹni to ba buwọlu ile yii, pẹlu gbogbo awsn ti o lọwọ ninu kiks ọ rẹ ni yoo foju wina ofin."

Gomina Wike to ṣe abẹwo si ile to wo naa ni ọjọ aiku ṣalaye gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba to lọwọ ninu rẹ pẹlu yoo jẹ iya gbogbo to ba tọ.

Image copyright @GovWike
Àkọlé àwòrán Eniyan mẹfa lo ti ku ninu ijamba ile naa

Wike wa rọ awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi to n ṣiṣẹ nibẹ lati maṣe kaarẹ titi ti wọn yoo fi yẹ tibu t'oro awoku ile naa lati doola ẹmi awọn ti o ṣi lee wa nibẹ.

Titi di asiko yii, eeyan mejidinlogoji ni wọn ti ko jade laaye labẹ awoku ile naa, ṣugbọn eeyan mẹfa miran ti ku.

Akọ̀ròyìn BBC tó dé bẹ̀ ní ènìyàn kan ló ti gbẹ́mìí mì tí wọ́n sì ti gbé àwọn mọ́kànlélógún tó fara pa lọ ilé ìwòsàn

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPortHarcourt pàdánù ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ẹ̀mí nínú ilé tó wó lulẹ̀

Ẹbí àwọn tó fara gbá níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ilé alájà méje tó wó ní ìlú PortHarcourt sọ fún BBC pé àwọn ènìyàn kan ṣì wà lábẹ́ ilé náà tó wó lọ́jọ́ kẹtàlélógún oṣù kọ́kànlá.

Ènìyàn kan ló ti bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn tí àwn adóòlà ẹ̀mí sì ti yọ ènìyàn méjìlélógún báyìí.

Image copyright Ile alaja meje, Port Harcourt
Àkọlé àwòrán Ile alaja meje, Port Harcourt

Ilé wo pà 'yàn meji l'Èkó

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIlé gogoro tí owó àgbẹ̀ kọ́

Àwọn òṣìṣẹ́ adóòlà ní lọ́jọ́ ẹtì ni àwọn yọ ẹni tó kú jáde tí wọ́n sì yọ ọkùnrin kan tí apá rl gé níbí ìṣlll náà ní agogo mẹ́rin òwúrọ̀ ọjọ́ àbámẹ́ta.

Ilé alájà méje náà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ lọ́wọ́ wó lulẹ̀ ní ọ̀nà Woji, GRA ní ìlú Port Harcourt tíi ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Rivers.

Image copyright RIVERS STATE GOVT HOUSE
Àkọlé àwòrán Ènìyàn tí wọ́n dóòlà

Àwọn tó fojú rí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní ó ṣẹlẹ̀ ní ǹkan bíi agogo márùn ún ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ ẹtì nínú èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ alágbàṣe àti àwọn ọlọ́jà pẹ́pẹ̀pẹ́ há sí.

Ní ǹkan bí agogo mẹ́jọ alẹ́ ọjọ́ ẹtì, wọ́n ti rí ènìyàn mọ́kànlélógún yọ wọ́n sì ti ń gba ìwòsàn báyìí.

Image copyright ORJI CHUKWUMELA KELVIN/FACEBOOK
Àkọlé àwòrán Àwọn ènìyàn níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Àkọ̀ròyìn BBC tó dé 'bi ìṣẹ̀lẹ̀ náà fàbọ̀ jẹ́ni pé àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera, òṣìṣẹ́ panápaná, ẹgbẹ́ alámì àgbélébùú àtàwọ́n òṣìṣẹ́ aláàbò míì ti wà níbẹ̀ láti túnbọ̀ dóòlà ẹ̀mí àwọ́n tó ṣì há sábẹ́ ilé náà.

Image copyright ORJI CHUKWUMELA KELVIN/FACEBOOK
Àkọlé àwòrán Àwọn ènìyàn níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà