World water day: Ẹrin Ijesa, Ọ̀ṣun Oṣogbo, àwọn ibùdó ìgbafẹ́ tí ó níi ṣe pẹ̀lú omi ní ilẹ̀ Yorùbá

Àkọlé fídíò,

Ẹrin Ijesa, Ọ̀ṣun Oṣogbo, àwọn ibùdó ìgbafẹ́ tí ó níi ṣe pẹ̀lú omi ní ilẹ̀ Yorùbá

Oniruuru ibudo irinajo afẹ lo wa ni ilẹ Yoruba lapa iwọ oorun gusu orilẹede Naijiria. Amọṣa lara wọn ni awọn ti o nii ṣe pẹlu omi wa.

Meji ninu awọn ibudo wọnyii ni a o mẹnuba ninu akọsilẹ yii; awọn meji naa si ni Orisun omi orioke Olumirin ti ọpọ mọ si Ẹrin Ijẹṣa Water falls ni ilu Ẹrin Ijẹṣa ati Ojubọ Ọṣun Oṣogbo ni ilu Oṣogbo, ipinlẹ Ọṣun kan naa.

1. Orisun omi orioke Olumirin ti ọpọ mọ si Ẹrin Ijẹṣa Water falls

Àkọlé àwòrán,

Ipele meje ni omi orisun apata Olumirin yii ti n jabọ

Ko si ẹni ti o ba de orisun omi Olumirin ni Ẹrin Ijẹṣa ti ko ni ya ẹnu si ayika rẹ.

Orisun omi orioke Olumirin ni orukọ rẹ ṣugbọn Ẹrin Ijẹṣa Water falls ni ọpọ mọọ si.

Itan sọ pe, ọkan lara awọn ọmọbinrin Oduduwa lo tẹdo si ibẹ lẹyin ti o ko awọn eeyan rẹ lẹyin kuro ni ile ifẹ

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn eeyan naa ni wọn ṣawari orisun omi orioke olumirin.

Gẹgẹ bii Ọba ilu naa, Ọba Isaac Ayẹni, Akila ti Ẹrin Ijẹṣa ṣe sọ, ọjọ meje ni o gba awọn baba bla wọn lati rin kuro ni ile Ifẹ deibudo ti omi naa wa.

O ni agbegbe naa wu awọn baba nla wọn ni wọn fi tẹdo sii.

Àkọlé àwòrán,

Ẹbun ayika to wuyi jọjọ ni oriosun omi orioke ẹrin Ijẹṣa naa jẹ

Nigbati wọn ri omi naa, o fa oju wọn mọra, wọn si ni oriṣa miran niyii, wọn pee ni 'olu miran'ni ede wọn, iyẹn "olumirin"

Ipele meje ni omi orisun apata Olumirin yii ti n jabọ

Oke meje ni eeyan yoo gun lati ri orisun rẹ gangan ni oke tente.

Àkọlé àwòrán,

Ọmọbinrin Oduduwa lo tẹdo sibi orisun omi orioke olumirin

Ko si ẹni to de ibudo igbafẹ yii ti ko ni fi ara gba afẹfẹ tutu minijọjọ

Ẹbun ayika to wuyi jọjọ ni oriosun omi orioke ẹrin Ijẹṣa naa jẹ.

Awọn igi elewe tutu ati ẹwa didara ti o yii ka kii jẹ ki ẹni to ba wa ni ibi orisun omi Olumirin o mọ ala pe oorun n mu rara.

2. Ojubọ Ọṣun Oṣogbo.

Àkọlé àwòrán,

Ajọ agbaye UNESCO ti kede Ọdun naa gẹgẹ bii ara awọn ọdun aṣa manigbagbe lagbaye

Ọdọọdun ninu oṣu kẹjọ ni ọdun Ọṣun Oṣogbo maa n waye ni ilu Osogbo.

Itan sọ pe ni ọpọ ọdun sẹyin ni awọn arinrinajo kan ti ọdẹ kan ti orukọ n jẹ Olutimẹhin ko sodi ni wọn tẹdo si eti odo Ọṣun.

Itan tun sọ pe iyan ti o mu ni ilu ti wọn wa tẹlẹ lo mu wọn mu irin ajo pọn lati wa ibi ilẹ gbe dara.

Àkọlé àwòrán,

Wundia ni o maa n ru igba etutu ọṣun

Itan naa tẹsiwaju pe, Ọṣun to jẹ oriṣa omi yii lo yọ si Olutimẹhim ti o si ke si oun atawọn eeyan rẹ pe ki wọn sun si apa oke diẹ, iyẹn nibi ti a n pe ni ilu Oṣogbo loni yii.

Ọṣun fi ara rẹ han gẹgẹ bii olu odo naa pẹlu ileri lati daabo bo wọn, ki o si mu awọn obinrin wọn maa bi sii bi wọn ba lee maa rubọ fun oun.

Loni irubọ naa ti kọja irubọ lasan, o ti di ajọyọ gbogbo agbaye.

Àkọlé àwòrán,

Ọdọọdun ninu oṣu kẹjọ ni ọdun Ọṣun Oṣogbo maa n waye

Kaakiri agbaye ni awọn eeyan ti maa n wa lati ṣe ọdun Ọṣun Oṣogbo.

Lati awọn orilẹede bii Amẹrika, Austria, Brazil, Cuba, Trinidad and Tobago, Jamaica, Spain Canada ati bẹẹbẹẹ lọ ni wọn ti n wa.Awọn miran jẹ ọmọlẹyin Ọṣun ninu wọn nigbati ọpọ si jẹ arinrinajo afẹ.

Ọsẹ meji ni wọn maa fi n ṣe ọdun ọṣun Oṣogbo.

Bi o tilẹ jẹ pe irinajo arugba lọ si idi odo ni o gbajugbaja julọ laarin awsn eeyan sibẹ oniruuru ayẹyẹ lo maa n waye lasiko ọdun naa.

Lara wọn ni:

  • Iwọpopo: eto ti wọn maa n ṣe lati gba ilu mọ kuro lọwọ ibi gbogbo. Ohun gan an ni o n ṣaaju ọdun Ọṣun osogbo.
  • Atupa olojumẹrindinlogun: titan atupa olojumẹrindinlogun eyi ti itan sọ pe o ti le ni ẹgbẹta ọdun ni yoo tẹlee. Ọjọ kẹta lẹyin iwọpopo ni eyi.
  • Ibọriade: Eyi ni etutu ti wọn n ṣe lati yẹ awọn Ọba ti wọn ti jẹ ṣaaju si.
  • Etutu arugba: Eleyi ti gbogbo agbaye fẹrẹ mọ niyi.

Pataki ninu eto ọdun yii ni arugba, iyẹn wundia ti ifa ba yan laarin awọn ọmọ ọba lati ru igba etutu ọdun eyi ti yoo gbe lọ si idi odo tilutifọn.

Susanne Wenger.

Àkọlé àwòrán,

Nǹkan méjì ló so Ẹrin Ijesa, Ọ̀ṣun Oṣogbo gẹ́gẹ́ bíi ibùdó ìgbafẹ́, ó sì yẹ kí o mọ̀ nípa rẹ̀

Ko si bi a ṣe lee sọ itan Ọdun Ọṣun Oṣogbo lai mẹnu ba arabing ọmọ orilẹede Austria ni, Susanne Wenger ti ọpọ mọ si Adunni oloriṣa. Ohun lo tun gbe ọdun naa larugẹ pẹlu ọpọlọpọ igbesẹ lati da ogo ojubọ rẹ pada lẹyin ọpọ ọdun ti awọn eeyan ti paa ti.

Nibayii, ajọ agbaye UNESCO ti kede Ọdun naa gẹgẹ bii ara awọn ọdun aṣa manigbagbe lagbaye.