Agbo: Ǹjẹ́ o mọ pàtàkì igi tó wà ní àyíká rẹ bí?

Agbo: Ǹjẹ́ o mọ pàtàkì igi tó wà ní àyíká rẹ bí?

Ọ̀pọ̀ ni kò mọ ìwúlò igi tí Elédùmarè fi jíǹkín àyíká rẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo igi ló ní ìwúlò rẹ̀ pàápàá fún ìlera àti ìṣègùn.

Lóòtọ́ àgbo ni oògùn àdáyébá ilẹ̀ Yorùbá, ṣùgbọ́n kò wọ́pọ̀ kí ènìyàn rí àwọn tí ó ń tàá ní àyíká tí ó farajọ ilé ìgbafẹ́ ìgbàlódé.

Bi o tilẹ jẹ wi pe ori ikiri abi ibudokọ ero ni eeyan ti n ri ọpọ alagbo ni ọpọ igba, ṣugbọn ero ibudo igbafẹ alagbo yii ṣe ara ọtọ nipa ti ayika ati imọtoto.

Ṣe wọn ni airinjinna ni airi abuke ọkẹrẹ, bi a ba rin titi a o ri ibi wọn gbe n fi odo ibilẹ jẹun.

Amọṣa, ẹ maa gbagbe pe ajọ NAFDAC nikan ni o laṣẹ lati fi ọwọ si ohun jijẹ tabi mimu lorilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: