Aminat Abiodun, Ìyálóde ilẹ̀ Ìbàdàn jáde láyé

Aminat Abiodun, Iyalode Ibadan

Oríṣun àwòrán, Olatunji Babatunde

Àkọlé àwòrán,

Gẹgẹ bi iyalode, ohun ni oloye Obinrin ti o ga julọ ni igbimọ lọbalọba ilẹ Ibadan

Iyalode ilu Ibadan, Oloye Aminat Abiọdun ti jade laye.

Iroyin ti o tẹ BBC News Yoruba lọwọ ṣalaye pe ni owurọ ọjọ abamẹta ni Iyalode Abiọdun ju awa silẹ.

Gẹgẹ bi iyalode, ohun ni oloye Obinrin ti o ga julọ ni igbimọ lọbalọba ilẹ Ibadan ni igba aye rẹ, Ọbabinrin ilẹ Ibadan ni wọn n pe iyalode Aminat Abiọdun. Ati owo, ọrọ ati agbara ni Iyalode ilẹ Ibadan fi ṣ'ọla.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ko si si ibi ti o lọ ti kiiṣe ari-ma-lee-lọ awo pada sẹyin ni wọn n woo nitori ẹwa rẹ.

Ni ọdun 2007 ni Alhaja Aminat Abiọdun gun ori oye iyalode ilẹ Ibadan lẹyin iku Iyalode to gbesẹ, Oloye Wuraọla Akintọla.

Aminat Abiọdun ni iyalode kẹtala ti o jẹ ni ilẹ Ibadan, ọdun kẹrindinlogoji ti o si bẹrẹ irinajo akasọ iyalode gẹgẹ bii jagun iyalode ni ọdun 1971 ni o togub ori oye.

Gbajugbaja oniṣowo pataki ni Iyalode Abiodun nigba aye yẹ. Alagbara ati ajafẹtọ araalu ni gẹgẹ bii awọn aṣiwaju rẹ bi Iyalode Ẹfunṣetan Aniwura ati Humani Alaga

Gẹgẹ bii iroyin ti o tẹ BBC News Yoruba lọwọ ṣe sọ, ni ọjọ aiku ni wọn yoo sin oku Iyalode Ilẹ Ibadan, Aminat Abiọdun ni ilana ẹsin Musulumi