2019 Elections: Omolara Adesanya olùdíje fún ipò Gómìnà fẹ́gbẹ́ PPC

Omolara Adesanya

Oríṣun àwòrán, Facebook/Omolara

Àkọlé àwòrán,

Idibo Gomina Ipinlẹ Eko

Omolara Adesanya jẹ obinrin to n dije fun ipo gomina nipinlẹ Eko labẹ asia ẹgbẹ osẹlu Providence People's Congress, PPC.

Omolara Adesanya jẹ ọmọ bibi ilu Eko. Lọjọ kẹtalelogun oṣu kẹfa ọdun 1957 ni wọn bii si idile Williams.

Ẹgbọn lo jẹ fun oloogbe oniwaasu Bimbo Odukoya to ku ninu ijamba ọkọ ofurufu lọjọsi.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Omolara

Àkọlé àwòrán,

Idibo Gomina Ipinlẹ Eko

O bẹrẹ si ni ṣiṣẹ pẹlu ile ifowopamọ orilẹede Naijiria(Central bank of Nigeria) ni bi ọdun marundinlogoji sẹyin lẹyin to ṣe iruulu tan pẹlu ilẹ iṣẹ ọhun.

Omolara fẹyin ti lọdun 2017 gẹgẹ bi ọkan lara awọn ọga nile ifowopamọ naa.

O bẹrẹ iṣẹ to yan laayo lati maa ṣeto inanwo ṣiṣe ni pẹrẹu.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Omolara

Àkọlé àwòrán,

Idibo Gomina Ipinlẹ Eko

Omolara gboye keji nile iwe giga fasiti ninu eto ẹkọ iṣowo. Oun ni oludari ile iṣẹ Royal Dainties Events, an event pla

nning and management to wa nile Eko.

Kolawole Adesanya lorukọ ọkọ rẹ, Ọlọrun ṣi fi ọmọ mẹta jinki wọn.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Omolara

Àkọlé àwòrán,

Kolawole Adesanya

Omolara kii sẹ oloṣelu nikan, oun tun jẹ olufọkansin nile ijọsin rẹ lagbegbe Ilupeju nilu Eko.

Omolara gbagbọ pe asiko ti to ti obinrin yoo jẹ gomina ipinlẹ Eko lẹyin ti awón obinrin ti jẹ igbakeji gomina ipinlẹ ọhun.

Oríṣun àwòrán, Twitter/ laraadesanya

Àkọlé àwòrán,

Idibo Gomina Ipinlẹ Eko

Omolara gbagbọ pe oun dantọ gẹgẹ bi obinrin lati tukọ ipinlẹ Eko, idi niyii to fi n dupo gomina.

Koda Omolara ko tun gbẹyin ninu ere idaraya, o ṣoju ipinlẹ Eko ni oriṣiriṣi idije ti o si gba ami ẹyẹ mẹtadinlogun lapapọ.