Naijiria: Ẹ wo iyé minisita tó ti kòwé fipò sílẹ̀ lásìkò Buhari

Muhammadu Buhari Image copyright @MBuhari
Àkọlé àwòrán Ní Ọjọ́ Kejila, Osù Kejila ni minisita fún ọ̀rọ agbèègbè fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ láti lọ jẹ́ Emir tí ìlú Nazarawa.

Minisita fun ọrọ agbegbe, Ibrahim Jubril, ni minisita karun un ti yoo fi ipo silẹ lati ọdun 2015 ti wọn ti bẹrẹ isejọba Aarẹ Muhammadu Buhari.

Jubril fipo rẹ silẹ lẹyin ti ẹgbẹ afọbajẹ ni Nazarawa fi jẹ Emir tuntun ni ipinlẹ naa.

Agbẹnusọ fun Aarẹ Buhari, Garba Shehu ṣalaye pe Buhari nikan lo le sọrọ lori ohun to n da yiyan minista tuntun duro.

O sọrọ yii fún BBC lasiko to n fesi si ibeere wi pe ki lo de ti Aarẹ Muhammadu Buhari ko i tii yan awọn minisita miran lati rọpo awọn minisita to kowe fipo silẹ lasiko isejọba rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mo ti gba kádàrá lórí bí Ọlọrun ṣe dá mi'

Shehu ni Aarẹ Muhammadu nikan lo le sọ asiko ti oun yoo yan awọn minisita ti yoo rọpọ awọn to fipo silẹ.

Minisita to ti fipo silẹ lasiko Aarẹ Buhari

Minisita marun un lo ti fi ipo silẹ lasiko aarẹ Muhammadu Buhari ti ko si tii yan ẹlomiran dipo wọn.

  • Hajiya Amina Mohammed ni Ọjọ kẹrinlelogun, Oṣu keji, ọdun 2017 ko iwe fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi minisita fun ọrọ agbegbe, lẹyin ti Ajọ Isọkan Agbaye (UN) yan an si ipo gẹgẹ bi igbakeji akọwe gbogboogbo fun ajọ rẹ.
  • Dokita Kayode Fayemi to jẹ gomina ipinlẹ Ekiti lọwọlọwọ lo fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi minisita fun ọrọ nkan alumọọni ni Ọgbọnjọ, Osu karun un, ọdun 2018 lati le lo ṣe eto oṣelu to gbe e wọle gẹgẹ bi gomina.
  • Ni ọjọ kẹrinla, Oṣu kẹsan an, ọdun 2018 ni minisita fun eto iṣuna, Kemi Adeosun ko iwe fipo rẹ silẹ lẹyin ti awuyewuye kan jẹyọ lori ẹsun wi pe ko ni iwe agunbanirọ ti awọn ọdọ fi n sin ijọba fun ọdun kan to pọn dandan ki eniyan to le se isẹ ijọba tabi ki o gba iwe ti o sọ pe o ti dagbaju lati se agunbanirọ.
  • Minisita fun ọrọ obinrin ati idagbasoke, Sẹnatọ Aisha Alhassan, ti awọn eniyan ma n pe ni Mama Taraba, fi ipo rẹ silẹ ninu ẹgbẹ oselu APC lori ẹsun wi pe wọn ko fun oun laye lati dije dupo gomina labẹ ẹgbẹ oselu APC ni ipinlẹ Taraba. Amọ, Mama Taraba na ti gba tikẹẹti lati dije dupo gomina labẹ ẹgbẹ oselu UDP ni ipinlẹ Taraba fun idibo gbogboogbo ti ọdun 2019.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mo ni baba isalẹ'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Aláàbọ̀ ara tó ń dari ọkọ̀ ojú pópó ní àìlera kìí ṣàrùn'