Shittu: Máà ṣiṣẹ́ tako olùdíje fún ipò gómìnà l'ábẹ́ APC ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ̀

Ṣaaju eto idibo abẹle ẹgbẹ naa ni aṣiri tu pe Shittu ko kopa ninu eto isinru ilu (NYSC). Image copyright @HMAdebayoShittu
Àkọlé àwòrán Ṣaaju eto idibo abẹle ẹgbẹ naa ni aṣiri tu pe Shittu ko kopa ninu eto isinru ilu (NYSC).

Alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, nipinlẹ̀ Ọyọ, Oloye Akin Ọkẹ ti fesi si ileri ti minisita Adebayọ Shittu jẹ́ lati ṣiṣẹ tako oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ́ naa l'Ọyọ.

Ọkẹ, ninu ọrọ to sọ fun BBC Yoruba nigba ti a kan si i lori ọrọ ti Shittu sọ yii sọ pe ''o jẹ ọkan lara awọn to janfaani eto idibo to kọja.

Sugbọn to ba jẹ wi pe nkan to pinnu lati ṣe niyi, a jẹ wi pe yoo ṣe aṣeyọri.''

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mo ti gba kádàrá lórí bí Ọlọrun ṣe dá mi'

Ọkẹ ṣalaye pe Shittu nikan kọ lo wa ninu ẹgbẹ ki wọn to o fa a kalẹ fun ipo minisita.

"To ba jẹ wi pe ẹsan to fẹ fi san ẹgbẹ niyẹn, o ku u, o ku Ọlọrun. Nitori pe ẹgbẹ wọle lo ṣe di minisita. Shittu jere ẹgbẹ ni, nitori pe oun nikan kọ lo wa ni ipinlẹ Ọyọ, ka to o fi jẹ minisita."

Lọjọru to kọja ni iroyin kàn pe Adebayọ Shittu to ti fi igba kan jẹ minisita fun eto ibaraẹnisọrọ l'orilẹede Naijiria, sọ pe oun yoo ṣiṣẹ tako oludije ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Adebayọ Adelabu, ninu eto idibo gomina ti yoo waye nipinlẹ Ọyọ l'ọdun 2019.

Shittu ti tikẹẹti ẹgbẹ ko ja mọ lọwọ, ni iroyin sọ pe o o sọ pe alaafia ko ni i jọba ninu ẹgbẹ APC.

Igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ APC ti gbe igbimọ kan kalẹ lati yanju wahala to n waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ ni ẹkùn idibo mẹfẹẹfa to wa ni Naijiria ṣaaju eto idibo to n bọ.

Lori eyi, alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọyọ, , Oloye Akin Ọkẹ sọ pe ohun to ba wu Shittu ni ko ṣe. To ba wu u, ko yọju si wọn, to ba wu u, ko ma yọju.

Ṣugbọn, gbogbo igbiyanju wa lati gbọ ọrọ lẹnu Adebayọ Shittu ni ko so eso rere, nitori pe pabo ni akitiyan wa ni gbogbo igba ti akọroyin BBC Yoruba pe e.

Minisita naa nikan kọ ni ọmọ ẹgbẹ APC to ti dun kooko lati ṣiṣẹ tako oludije ẹgbẹ naa fun ipo gomina lasiko eto idibo gbogboogbo ti yoo waye l'ọdun 2019.

Gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun, ati akẹẹgbẹ rẹ ni ipinlẹ Imo, Rochas Okorocha, naa ti sọ bẹ ẹ nitori pe tikẹẹti ẹgbẹ ko ja mọ awọn oludije wọn lọwọ lati dije fun ipo gomina.

Image copyright @Govsia
Àkọlé àwòrán Gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun, ati ti Imo, Rochas Okorocha, naa ti pe awọn yoo ṣiṣẹ tako ẹgbẹ́ APC.

Shittu fi ẹsun kan gomina ipinlẹ Ọyọ, Abiọla Ajimọbi, ati alaga gbogboogbo fun ẹgbẹ APC, Adams Oshiomole pe awọn lo wa nidi bi oun ko ṣe ri tikẹẹti gba.

Ṣugbọn ṣaaju eto idibo abẹle ẹgbẹ naa ni aṣiri tu pe Shittu ko kopa ninu eto isinru ilu (NYSC) to maa n waye fun gbogbo awọn akẹkọ jade ni Naijiria.