Ṣọla Kosọkọ: ọlá bàbá mi ni mò n jẹ́ nínú iṣẹ́ tíátà

Ṣọla Kosọkọ: ọlá bàbá mi ni mò n jẹ́ nínú iṣẹ́ tíátà

O ni iṣẹ́ agbẹjọro gangan ló wu oun láti kà ni fasiti tẹ́lẹ̀, iṣẹ́ orí rán kaluku ló n ṣe.

Ogbontarigi oṣere-binrin, Ṣọla ọmọ Jide Kosọkọ aya Abina ba BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ lori iṣẹ tiata ti o yàn laayo.

Ogidi ọmọ Yoruba ti ede Yoruba dáńtọ́ lẹnu rẹ nigba ti o n ba BBC sọrọ ti kò tun tijú lati sọ èdè abinibi rẹ mẹnuba ipa rere ti ipò baba rẹ kó ninu idagbasoke iṣẹ tiata ti oun n ṣe.

Ṣọla Kosọkọ-Abina gboriyin fawọn ọga agba elere tiata ti ko filọkulọ lọ oun lẹnu iṣẹ́ nigba to n sọ bi baba rẹ, Jide Kosọkọ ṣe bẹrẹ ere lọmọ ọdun mẹwaa péré ṣaaju ko to bi oun.

O ni kíkó ipa ṣiṣe aṣẹwo, ọmọ ọlọja irọle lo jẹ ipenija to le julọ fun oun ninu iṣẹ tiata..

Bakan naa lo mẹnuba àwọn ọrẹ to ni to pọ ṣugbọn to jẹ pé ọ̀tọ̀ ni aaye ti oun fi oṣere-binrin Doris Simeon si.