Timi Frank: Àjọ UN, EU ẹ báwa kìlọ fún Ààrẹ Buhari

Buhari ati Timi Frank Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Igbákejì Akọ̀wé ẹgbẹ́ òsèlú APC tẹ́lẹ̀rí, Timi Frank ní Buhari ń ni àwọn ẹgbẹ́ alátakò,PDP lára.

Igbakeji akọwe ẹgbẹ oselu APC tẹlẹri, Timi Frank ti kesi Aarẹ Muhammadu Buhari wi pe ko ti ọwọ ọmọ rẹ bọ asọ lori isesi rẹ si awọn alatako.

Timi Frank to fi atẹjade sita wa kesi orilẹede Amẹrika(US), Ilẹ Gẹẹsi(UK), Ajọ Isọkan Agbaye(UN) ati Ajọ Isọkan Europe(EU) lati kilo fun Aarẹ Buhari ko dẹkun iwa ifiyajẹ awọn ẹgbẹ alatako.

Igbakeji akọwe ẹgbẹ APC tẹlẹri naa ni ohun ti ko ba ofin mu ni bi wọn se fi panpẹ ọba mu Doyin Okupe, ti wọn si lọ se‘abẹwo ti ko tọ’ si ile ọmọ Atiku Abubakar to jẹ oludije si ipo aarẹ ni ẹgbẹ oselu APC.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSola Kosoko: ọlá bàbá mi ni mò n jẹ́ nínú iṣẹ́ tíátà

O fikun wi pe wọn tun ti fẹ fi panpẹ ọba mu alaga ile ifowopamọsi Fidelity Bank, Nnamdi Okonkwo nitori wi pe Peter Obi to n dije dupo igbakeji aarẹ ni PDP jẹ alaga banki naa tẹlẹ.

Timi Frank lo fi ẹgbẹ oselu APC silẹ ni Osu Kẹjọ, ọdun 2018 peẹu ileri wi pe oun ko ni dakẹ lati ma sọrọ tako iwa ibajẹ lawujọ.