Femi Okunronmu: Parliamentary pé wa ju ìṣèjọba presidential lọ

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFemi Okunronmu: Parliamentary pé wa ju ìsàjọba presidential lọ

Gbajugbaja oloselu, Femi Okunronmu ti kan saara si awọn asofin to buwọlu abadofin to fi agbara fun isejọba igbimọ awọn aṣofin (parliamentary) lati rọpọ iṣejọba to fi agbara fun aarẹ.

Femi Okunronmu to sọ eyi lasiko to n ba BBC sọrọ ni awọn eniyan bii ti oun to n ja fun atunto Naijiria naa ti n ja fun isejọba to fi agbara fun awọn asofin lorilẹ-ede Naijiria tipẹ́

Ninu ọrọ rẹ, isejọba to fi agbara fun awọn aṣofin yoo fun awọn ara ilu ni anfaani lati le kopa ninu iṣejọba ilẹ wọn, eleyii to yatọ si eyi to fi agbara fun aarẹ nikan ṣoṣo lọ.

Anfaani wo lo wa ninu iejọba Parliamentary to fi ju Presidential lọ?

Femi Okunronmu sọ pe ni ilẹ Afirika, iṣejọba awọn amofin lo le kapa bi awọn adari ni ilẹ Adulawọ se fẹran lati maa di ipo mu fun ọpọlọpọ igba. O salaye awọn anfaani to wa nibẹ;

  • Isejọba aarẹ gbe gbogbo agbara fun aarẹ (Executive Power), sugbọn ti isejọba igbimọ aṣofin gbe agbara fun gbogbo awọn aṣofin ti wọn dibo yan.
  • Owo iṣejọba awọn amofin ko pọto ti isejọba aarẹ.
  • Ki eniyan too ṣe minisita labẹ isejọba awọn amofin, awọn eniyan gbọdọ dibo yan ẹni naa ni ẹkun rẹ, amọ aarẹ le yan ẹni to wu u si ipo minisita.
  • Ẹgbe alatako ni agbara lopolopo, ti won ko si ni bo iwa ibaje mọlẹ bi o ṣe wọpọ ni isejọba aarẹ.
  • Owo ipolongo lasiko idibo ko pọ rara bii ti isejọba aarẹ ti o nilo ọpọlọpọ owo lati se ipolongo, eleyii ti o n mu ọpọlọpọ oloselu jale lati di ọjẹlu.
  • Ọsọọsẹ tabi osoosu ni Olotu ijọba isejọba amofin yoo ma jabọ fun awọn ara ilu, eleyii ti ko wọpọ ni isejọba aarẹ.

Femi Okunronmu wa gba awọn ọmọ Naijiria ni iyanju lati gbaruku ti awọn asofin ti wọn buwọlu abadofin naa, ki igbe aye irọrun le ba awọn ọmọ Naijiria.