Linda Ikeji: Sholaye ni bàbá ọmọ mi, ṣùgbọ́n a ti túká

Linda Ikeji Image copyright officiallindaikeji/Instagram
Àkọlé àwòrán Linda ati ọkọ rẹ tuka

Ilumọka oniroyin ayelujara Linda Ikeji ti ṣafihan ọmọkunrin jojolo rẹ lori ayelujara, bẹẹ ni o si fidi rẹ mulẹ pe jayejaye oun ko ni nnkankan ṣe mọ pẹlu baba ọmọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Sholaye Jeremi.

Laarọ ọjọ Ẹti ni Linda fọrọ naa lede loju opo Instagram ati opo ayelujara tirẹ gan an, Lindaikejisblog.

Linda ni Jayce lorukọ ọmọ naa ti o ṣapejuwe gẹgẹ bi ẹbun to dara julọ t'oun ri gba lati ọdọ Ọlọrun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSola Kosoko: ọlá bàbá mi ni mò n jẹ́ nínú iṣẹ́ tíátà

Lọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹsan an ọdun 2018 yii ni o bi ọmọ naa silu Atlanta lorilẹede Amẹrika nigba ti o ku ọjọ meji ti oun gan an yoo pe ọmọ ọdun mejidinlogoji.

Linda tun ṣalaye bi oun ati Sholaye ti pade ara wọn, bakan naa lo ṣalaye bi ọrọ ti bẹyin yọ ti onikaluku ṣi fi ba tirẹ lọ.

O ni kii kiku ṣe wi pe oun fẹran lati maa ni ọkọ lori, ṣugbọn ọrọ yipada nigba ti Sholaye yọwọ iwa si oun. O ni Sholaye dẹkun fifi atẹjiṣẹ ọrọ ifẹ ranṣẹ si oun, bẹẹ ni ko si pe oun mọ lori ago.

O ni Sholaye tun sọ fun oun pe ẹru n ba oun lati foun ṣaya nitori ilumọka ni oun jẹ. O ni bi o ti n sa fun oun ni oun tun waa lọ.

Linda fi kun un ọrọ rẹ pe o tiẹ buru tan patapata nigba ti oun loyun tan fun Sholaye.

O ni oun ko ni gbagbọ ti ẹnikan ba sọ fun oun pe Sholaye maa yipada lẹyin ti awọn ti mọ ara awọn fun ọdun mẹta ti awọn si jọ gbero lati fẹ ara awọn bi tọkọ taya.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mo ti gba kádàrá lórí bí Ọlọrun ṣe dá mi'