FRSC: Awakọ̀ tó bá tàpá sófin ojú pópó yóò ṣọdún lẹ́wọ̀n

Oṣiṣẹ FRSC Image copyright Twitter/FRSC Nigeria
Àkọlé àwòrán Ọrọ ofon oju popo

Bi pọpọṣinṣin ọdun Keresi ati ọdun tuntun ti n kanlẹkun, ajọ to n risi aabo loju popo(FRSC) ti kede pe ile-ẹjọ alagbeka fawọn to ba tako ofin oju popo yoo bẹrẹ lọjọ Aje.

Ọga agba ajọ FRSC Ọmọwe Boboye Oyeyẹmi lo fọrọ naa lede lọjọ Satide nigba to ṣabẹwo silu Ibadan lati rii pe ko si idiwọ kankan fun lilọ-bibọ ọkọ kaakiri orilẹede Naijira.

O fi kun ọrọ rẹ pe ẹnikẹni to ba tapa sofin irina yoo ṣe ọdun Keresi ati ọdun tuntun rẹ lọgba ẹwọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni awọn oṣiṣẹ ajọ FRSC ti wa ni igbaradi lati rii pe ẹnikẹni to ba tapa si ofin irina ko ni lọ lai jiya ẹsẹ rẹ.

Image copyright Twitter/FRSC NIgeria
Àkọlé àwòrán Ọrọ ofon oju popo

Ọga ajọ FRSC tun rọ awọn awakọ lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn oṣisẹ eto aabo loju popo bi ọdun ti mbọ wa sopin.

Ọmọwe Oyeyẹmi rọ awọn awakọ pe ki wọn maa sa ere asaju, bẹẹ lo ṣeleri pe ẹṣọ oju ọna lati de ibi kibi ti ijamba ọkọ ba ti ṣẹlẹ tabi ti sunkẹrẹ fakẹrẹ ba wa niṣẹju akan.