Ìjàmbá ọkọ̀: Àpótí ìkẹ́rùsí jálu ọkọ̀ méjì lórí l'Eko

Ijamba ọkọ Image copyright Twitter/FRSC
Àkọlé àwòrán Ijamba ọkọ

Iroyin to tẹ wa lọwọ lo ṣo pe apoti ikẹru si(container) lo ja lu ọkọ meji lagbegbe Maryland nilu Eko lọjọ Abamẹta.

Ọkọ Toyota Avalon ati Villager minivan ni awọn ọkọ mejeeji ọhun.

Image copyright Twitter/FRSC
Àkọlé àwòrán Ijamba ọkọ

A o le sọ boya ẹmi ba isẹlẹ naa lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọga ajọ to n ri si ọrọ pajawiri nipinlẹ Eko Adesina Tiamiyu ṣalaye pe ọkan ninu awọn ọkọ ọhun tiẹ tun gbina.

Image copyright Twitter/FRSC
Àkọlé àwòrán Ijamba ọkọ

Ẹnikan ti isẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ pe awọn tọkọ taya ti wọn wa ninu ọkan ninu awọn ọkọ ọhun mori bọ

Ẹlomiran tun sọ pe ẹni to wa ọkọ keji wa lẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun.