Ayinde Barrister: Òní ló pé ọdún mẹ́jọ ti ọba orin jáde láyé

Oloogbe Ayinde barrister Image copyright Facebook/Barrister fans page
Àkọlé àwòrán Iku mu ọba orin Fuji lọ

Iku n pani, ilẹ n jẹyan. Oni lo pe ọdun mẹjọ geerege ti ilumọọka olorin Fuji, Alhaji Sikiru Ololade Ayinde Balogun Barrister jade laye.

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kejila, ọdun 2010 ni Barrister dagbere faye ni ile iwosan kan nilu London.

Ẹbi. ọrẹ ati awọn ololufẹ rẹ ni wọn n ṣeranti Barrister lonii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lori opo Twitter ọkan ninu awọn ololufẹ Barrister gbadura pe ki olorin naa ko maa sun laya Olugbala lọ

Ọmọ ọba Ademolateejay ni ṣe lo dabi ana ti Ayinde Barrister faye silẹ lọdun mẹjọ sẹyin, o ni iku olorin Fuji naa dabi oguta iyebiye to sọnu.

Moruff Adenekan ni tirẹ sọ pe Barrister ti sọ asọtẹlẹ nipa awọn ipenija to n dojukọ eto oṣelu ati ọrọ aje Naijiria ninu awo kan to gbe jade ṣaaju idibo gbogbogbo ọdun 1983, bẹẹ lo si ṣalaye ọna abayọ.

O ni ọpọ ko ka a kun nitori ede Yoruba lo fi kọ orin naa.

Lori Facebook, Abu Mutalubi Omobolaji ni awọn ololufẹ Barrister n ṣeranti ẹni re to lọ. O gbadura pe ki ọba orin ko maa sun lọ laya Olugbala.

Image copyright Facebook/Barrister fans page
Àkọlé àwòrán ṣe ẹyin ranti orin kekere arosọ?

Idris Olawuyi n ṣe'ranti Barrister pẹlu orin to fun ra rẹ kọ pe b'iku ṣe lagbara to ko si oloogun to ri tiku ṣe.

Image copyright Facebook/Barrister Fans page
Àkọlé àwòrán Opo ko kọkọ gbagbọ nigba ti wọn kede iku Barrister

Ololufẹ Barrister mii gbadura ni pe ki Alhaji Agba maa sinmi laya Allah titi di ọjọ agbende.

Image copyright Facebook/Barrister Fans page
Àkọlé àwòrán ọjọ kan nina a dilẹ leyin gbogbo asunsu je laye

Fun ọmọ ọba Ọmọ Ọla, o ni ọgbẹ ọkan ti iku Barrister da si ọkan awọn ololufẹ rẹ si tun wa laya oun. O fikun ọrọ pe o le maa si olorin Fuji bi Barrister mọ laye.

Image copyright Facebook/Barrister Fans page
Àkọlé àwòrán Ko sẹni ti ko ni ku ni Yoruba n wi
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption''Ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣì n sọnù ni orilẹ̀-ede Burundi'