Ẹgbẹ ọmọ Yorùbá kí Gomina Abiola Ajimobi kú oríire ọjọ́ ìbí

Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ọmọ bibi ilẹ Ibadan, Central Council of Ibadan Indigenes(CCII) n ṣe akanṣe eto igbalejo fun ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mọkandinlaadọrin ti gomina ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi.

Ibadan
Àkọlé àwòrán Ọpọlọpọ awọn ẹbi, ara, ọrẹ lo pejọpọ si ibi ayẹyẹ ọjọ ibi ti agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ọmọ bibi ilẹ Ibadan, Central Council of Ibadan Indigenes(CCII) se fun Gomina ipinlẹ Ọyọ.
Ibadan
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹjẹgbẹ ati awọn iyalode naa kọ gbẹyin nibi ayẹyẹ ojo ibi ọdun mọkandinlaadọrin ti gomina ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi.
Ibadan
Àkọlé àwòrán Akaara oyinbo ti wọn fi ohun elo orin bii gangan ati sẹkẹre se naa o gbẹyin
Ibadan
Àkọlé àwòrán Awọn adari ile ijọsin ati awọn Alfa ati imamu naa wa ba Gomina Abiọla Ajimobi se ẹyẹ ọjọ ibi.
Ibadan
Àkọlé àwòrán Awọn kabiyesi, lade-lade ati loyeloye naa wa nibẹ.
Ibadan
Àkọlé àwòrán Igbakeji Gomina ipinlẹ Ọyọ, Moses Adeyẹmọ naa n bẹ nibẹ.
Ibadan
Àkọlé àwòrán Awọn alasọ ẹbi ẹlẹgbẹjẹgbẹ lawujọ ati ni ipinlẹ Ọyọ naa ko gbẹyin nibẹ.
Ibadan
Àkọlé àwòrán Abike Dabiri-Erewa to jẹ oluranlọwọ pataki fun Aarẹ Buhari lori ọrọ ilẹ okeere naa wa yẹ goimina Ajimọbi si
Ibadan
Àkọlé àwòrán Awọn elere ibiẹ to n fi gangan dabira naa o gbẹyin nibẹ.

Ile isẹ iroyin BBC lo ni awọn aworan yii.