Alápinni: Ìjọba kò gbárùkù tì wá nínú iṣẹ́ tíátà

Alápinni: Ìjọba kò gbárùkù tì wá nínú iṣẹ́ tíátà

'Ilẹ̀kùn tó wọ eré tìátà ti pọ̀ jù lásìkò yìí'

Gbajugbaja oṣere, Ganiu Nafiu ti gbogbo eeyan mọ si Alapinni Ooṣa sọrọ nipa idojukọ ti ẹgbẹ oṣere n koju lori ayederu ẹda fiimu ti wọn n pe ni 'Piracy'.

O ba BBC Yoruba sọrọ lori ọna ti àwọn àsáwọ̀ oṣere ṣe n wọ agbo wọn nigba ti BBC Yorùbá n fọrọ waa lẹnu wo ni Port Novo lorilé-ede Bẹnin Republic.

O ni ijọba Naijiria kò ba àwọn oṣere ja ija naa bi o ti yẹ pe ohun lo faa ti onikaluku fi n dọmu iya rẹ gbe.

Alapinni Ooṣa ṣalaye ipa pataki ti àwọn baba nla tiata bii Hubert Ogunde ko nigba aye wọn ni eyi ti o fi jẹ pe kikọ ni mímọ̀ ni wọn n fi ọrọ iṣẹ ere ori itage ṣe ni akoko naa.

O kilọ wiwa òkìkí ti àwọn àsáwò inu ere tiata kọọkan n wa lasiko yii fun wọn.

Alapinni rọ awọn eniyan ki wọn farabalẹ kọ iṣẹ ti wọn ba yan laayo ki wọn le di agba ọ̀jẹ̀ nibẹ koda ko ṣe iṣẹ tiata.

Bakan naa lo parọwa pe ki gbogbo eeyan sọ ogun ayederu ẹda nkan ti a mọ si 'Piracy' di ogun àjùmọ̀jà.