#Sima Sarkar 'Yorùbá gbà pé òrìṣà bí ìyá kò sí!'

#Sima Sarkar 'Yorùbá gbà pé òrìṣà bí ìyá kò sí!'

Hridoy Sarkar tó jẹ ọmọ ọdún mejidinlogun ni ọmọ gende náà ti iya rẹ pọn ti aworan wọn jade lori ayelujara kaakiri.

BBC lọ ṣe iwadii nipa Sima Sarkar ati ọmọ rẹ Hridoy ti àwòrán wọn jade lori bi iya rẹ ṣe pọn ọmọ ọdun mejidinlogun naa sẹyin lọ ṣe idanwo aṣewọle si fasiti Dhaka.

Fun iwuri gbogbo awọn to gbọ Hridoy Sarkar ṣe aṣeyọri ninu idanwo naa si idunnu iya rẹ.

Sima ṣalaye nipa ọmọ rẹ pe akanda ẹda ti kò le sọrọ, to oun nilo lati maa ṣe gbogbo nkan fun ni Hridoy.

Sugbọn afojusun oun lọjọ iwaju ni pe ki Hridoy le da ṣe nkan fun ra rẹ lẹyin to ba kawe jade nile ẹkọ giga naa tan.

O gba pé ilakaka oun yoo ja si ọpẹ ati ayọ ti ọmọ naa ba le da ṣe aye rẹ lẹyin iku oun.

O gba awọn obi akanda ẹda nimọran pé ki wọn ma jẹ ki awọn ọmọ bẹẹ ro pe iṣoro ni awọn jẹ ninu ile fun ẹbi.

Sima Sarkar sọrọ lori bi oun ṣe maa n ṣiṣẹ ile ati iranlọwọ ti ọkọ oun n ṣe ki ọjọ ola Hridoy le dara lai naani pẹ akanda ẹda ni.