Access Bank ti gba ilé ìfowópamọ́sí Diamond Bank

ACCESS ATI DIAMOND BANK Image copyright FACEBOOK
Àkọlé àwòrán Ẹ̀rọ̀ àwọn ọmọ Naijiria se ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí bí ilé ìfowópamọ́sí Diamond se darapọ̀ mọ́ ile iilé ìfowópamọ́sí Access.

Ibeere to n suyọ lẹnu awọn ọmọ Naijiria ni wi pe kini yoo sẹlẹ si isẹ awọn osisẹ Diamond Bank, lẹyin ti ile ifowopamọsi naa kede wi pe awọn yoo darapọ mọ ile ifowopamọsi Access.

Ni Ọjọ Aje ni awọn adari ile isẹ Diamond Bank naa kede idarapọ mọ ile isẹ Access Bank.

Ninu ọrọ ti wọn fi lede, ki o to di Osu Kẹfa, ọdun 2019 ni awọn yoo pari gbogbo eto lati se idarapọ mọ Access Bank.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYorùbá gbà pé òrìṣà bí ìyá kò sí!

Kini yoo sẹlẹ si awọn osisẹ Diamond Bank?

Awọn ọmọ Naijiria lori ẹrọ ikansiraeni Diamond Bank lori opo Twitter ti n fesi bi Diamond se darapọ mọ Access Bank.

Ọpọ ninu wọn n bere wi pe njẹ awọn osisẹ Banki naa ko ni dii alainisẹ lẹyin ti wọn ba ti darapọ mọ Access Bank.

Bakan naa ni awọn eniyan kan n bere wi pe ẹni to ba n lọ banki mejeeji, kini yoo sẹlẹ si wọn?

Awọn miran ti lẹ n se awada wipe se Access Bank yoo tun gba oju opo ikansiraẹni Twitter ti Diamond Bank.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGbogbo ènìyàn ló wọ agbádá ikú, ẹni tó kàn lẹnìkan kò mọ̀

Igba akọkọ kọ ni yii ti ile isẹ ifowopamọsi Access yoo ma gba banki miran mọra. Ọdun 2011 si 2012 ni wọn gba Intercontinental Bank Plc, ti wọn si fi ọwọ osi juwe ile fun ọpọlọpọ awọn osisẹ banki Intercontinental naa ki wọn to darapọ mọ ile ifowopamọsi Access Bank.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAlápinni: Kò sí ẹni to fẹ́ kọ́kọ́ kọ́ iṣẹ́ òṣèré bíi ti àtẹ̀yìnwá
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCJ Gold: ẹ̀rù kọ́ka ba ìyá mi nígbà ti mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìjà jíjà