#2019NigeriaDecides: Oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn tí àwọn olúṣèlú ń pín

Ninu eto oṣelu orilẹ-ede Naijiria, gbogbo ọna ni awọn oludije maa n gba lati rii pe awọn eeyan dibo fun wọn nigba idibo.

Oriṣiriiṣi nkan ni awọn oloṣelu maa n pin fun awọn eeyan yala ki idibo too de, tabi ninu eto idibo ati lẹyin idibo ki wọn le dibo fun wọn.

Oríṣun àwòrán, Valour Digest

Àkọlé àwòrán,

Ẹbun awọn oloṣelu

Koda ọpọlọpọ lo ti maa n foju sọna si asiko idibo nitori igba yẹn ni awọn oloṣelu maa n pin oriṣiriiṣi nnkan fawọn eeyan. Diẹ lara irufẹ awọn ẹbun bẹẹyii.

Awọn oloṣelu kan wo pe tebi ba tan ninu iṣẹ. iṣẹ bu sẹ. Eyi lo mu wọn din akara fawọn eeyan jẹ ki wọn le dibo fun wọn.

Gomina Ipinlẹ Benue ti ẹ ya awọn eeyan lẹnu nigba ti o pin ''wheel barrow'' to kọ orukọ rẹ si fun awọn ara ipinlẹ naa. Bo tilẹ jẹ pe o ni oun o mọ nkankan nipa rẹ.

Lẹyin naa lo ni ki wọn ko awọn ''wheel barrow'' naa nilẹ ṣugbọn iroyin naa ti kaakiri.

Oríṣun àwòrán, Twitter/OrderPaper

Àkọlé àwòrán,

Ẹbun awọn oloṣelu

Ọkan lara awọn sẹnẹtọ to n ṣoju ipinlẹ Kaduna Shehu Sani naa gbarada nigba ti o pin redio kekeke fun awọn eeyan to nikaluku si to lori ila ti wọn gba lọkọọkan.

Bẹẹ ni ko si sọ pe oun kọ l'oun wa ninu fọto to n pin redio fawọn eeyan.

Oríṣun àwòrán, Omojuwa.com

Àkọlé àwòrán,

Awọn ohun ti wọn n pin lasiko idibo

Ninu awọn oloṣelu ti wọn maa n pin oriṣiriṣi ẹbun fun awọn oludibo, ọkan ni gomina ana ipinlẹ Ekiti Ayo Fayoṣe jẹ.

Fayoṣe ti pin ẹbun bi irẹsi, miliki, ororo ati iṣebẹ fawọn eeyan rii. Ṣugbọn o ṣe ohun to ya ọpọ lẹnu nigba ti o bẹrẹ si pin adiyẹ fawọn eeyan.

Oríṣun àwòrán, Ayodele Fayose

Àkọlé àwòrán,

Ayo Fayoṣe pin ẹbun adirẹ

Ninu idibo gomina ipinlẹ Ondo lọdun 2016, burẹdi pẹlu akọle ''AKẸTI'' gbode kan nipinlẹ ọhun lati fio ṣe ipolongo idibo fun Rotimi Akeredolu to jẹ oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ẹgbẹ alatako ni burẹdi majele ni burẹdi ọhun, iyẹn o ni ki wọn kuku ko burẹdi ọhun nilẹ

Oríṣun àwòrán, The Gong

Àkọlé àwòrán,

Burẹdi ni wọn pin ni ipinlẹ Ondo

O dabi ẹni pe awọn olosẹlu lorilẹ-ede Naijiria tilẹ mọ pe ebi n pa ọpọlọpọ, iyẹn lo jẹ ki aarẹ ana Goodluck Jonathan ati Namadi Sambo pin gari ati ẹpa pẹlu ṣuga nigba ti wọn n polongo fun idibo aarẹ ọdun 2015.

Fọtọ awọn mejeeji lo wa lara ọra ti wọn ko gbogbo nnkan ọhun si.

Oríṣun àwòrán, Jonathan-Sambo

Àkọlé àwòrán,

Idibo aarẹ ọdun 2015

Raisi jẹ ọkan lara ounjẹ to wọ pọ ni Naijiria. Bẹẹ naa ni awọn oloṣelu fẹran lati maa pin iresi lasiko idibo.

Gomina ana ipinlẹ Ọṣun, Rauf Arẹgbẹsọla pin irẹsi fun awọn ololufẹ rẹ lasiko idibo gomina nipinlẹ Oṣun.

Irẹsi Arẹgbẹ ni wọn kọ gbagada sara apo ti wọn fi di irẹsi ọhun.

Oríṣun àwòrán, Rauf Aragbesola

Àkọlé àwòrán,

Ẹbun nigba ibo gomina ipinlẹ Oṣun

Àkọlé fídíò,

#BBCNigeriaElections: Ọmọ Ogun iṣẹ́ yá -Adarí àjọ elétò ìdìbò Ogun

Ounjẹ kan ti awọn ọmọde fẹran ni nudu ti ọpọ maa n pe ni Indomie. Koda awọn agba miran naa fẹran ounjẹ yii.

Nudu ko ṣoro lati se rara, boya iyẹn lo jẹ ko wọ pọ ni pinpin lagbo oṣelu. Ọpọlọpọ ẹgbẹ lo maa n pin nudu ti wọn o si kọ orukọ ẹgbẹ oṣelu wọn sori ọra ti wọn fi dii.

Oríṣun àwòrán, PDP

Àkọlé àwòrán,

Ẹbun ounjẹ ti awọn oloṣelu n pin

Àkọlé fídíò,

Afẹnifẹre ni ọrọ atunto lawọ́n tori ẹ yan Atiku laayo

Ko si ẹni ti ko nilo ọṣẹ ninu ile yala lati fi wẹ tabi lati fi fọ abọ.

Ẹgbẹ oṣelu APC gbarada lẹyin ti wọn di ọṣẹ iwẹ ati ifọ aṣọ sinu ọra ti wọn si pin fawọn eeyan lasiko ipolongo idibo.

Oríṣun àwòrán, APC

Àkọlé àwòrán,

Ẹbun ọṣẹ ẹgbẹ oṣelu APC

Awọn olosẹlu kan tilẹ ba debi wi pe wọn tun pi kaadi pipe eeyan lori ago. Gomina ana Akinwunmi Ambọde wa lara awọn to pin orufẹ ẹbun yii nigba ipolongo oṣelu idibo gomina nipinlẹ Eko.

Oríṣun àwòrán, APC

Àkọlé àwòrán,

Ẹbun kaadi lasiko idibo