Nigerian Army: Awọn agbẹbọn pa ọ̀gágun tẹ́lẹ̀ Alex Badeh

Alex Badeh Image copyright Nigerian Army
Àkọlé àwòrán Iku pa oga ologun

Iku ogun nii pa akinkanju, iku odo ni pa omuwẹ.

Àwọn agbébọn kan tí gbẹ̀mí Ọ̀gágun àgbà tẹ́lẹ̀ fún iléeṣẹ́ ọmọ ogun òfúrufú Nàìjíríà, Alex Badeh.

Alukoro fun ile iṣẹ ologun ofurufu, Commodre Ibikunle Daramola to fidi ọrọ naa mulẹ

Iroyin sọ pe nigba ti o n bọ lati oko rẹ lopópónà Keffi sí Abuja ni wọ́n tí dáa lọ́nà tí wọ́n sí dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò.

Koda iroyin ni wọn tun yinbọn pa awakọ rẹ pẹlu.

Kini o yẹ koo mọ nipa Badeh?

Omo bibi ipinlẹ Adamawa ni ọgagunfẹyinti Alex Badeh jẹ.

O lo ọdun mejidinlogoji lẹnu iṣẹ ologun ko to fẹyinti ninu iṣẹ ologun ni oṣu keje, ọdun 2015.

O jẹ ajagunfẹyinti nileeṣe ologun ofurufu, eyi to jẹ adari agba fun ni 2012 si 2014

Oun ni o jẹ olori ikọ ọlogun apapọ to n daabo bo Naijiria lọdun 2014 si 2015.

Wọn fi ẹsun kan an pé o kowo jẹ ni eyi ti ajọ to n gbogun ti iwa ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu EFCC n ṣe iwadii rẹ lọwọ lati oṣu keji, ọdun 2016. Wọn ni o na owo to yẹ ki wọn fi ra ohun eelo ijagun ni inakuna.

Bakan naa lo jẹ adari PAF to jẹ awọn to n mojuto ọkọ ofurufu ile iṣe aarẹ lọdun 2002 si 2004.

O jẹ adari ẹka ile iṣe ologun fun iṣe akanṣe pẹlu ọpọlọ pipe NDC ni ọdun 2006.

Ogagun Alex Badeh gbe Mary Iyah niyawo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Tayọ̀tayọ̀ ni mó fẹ́ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú INEC ki ìdìbò 2019 lé dára'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAlápinni: Kò sí ẹni to fẹ́ kọ́kọ́ kọ́ iṣẹ́ òṣèré bíi ti àtẹ̀yìnwá