Ogun APC: Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú fìjà pẹ́ta pẹ̀lú awọn agbófinro

Image copyright @OgunAPCOfficial
Àkọlé àwòrán Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ oṣèlú gbéna wojú awọn agbófinro

Ọ̀rọ̀ ṣe bí ọ̀rọ̀ lónii ọjọ́bọ̀ ní olú ilé-iṣẹ́ àwọn elétò ìdìbò (INEC) bí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) láti ẹkùn ìdìbò Yewa ní ìpínlẹ̀ Ogun ṣe gbéná wojú àwọn agbofinro.

Àwọn afẹ̀hónú hàn ọ̀hún to tó igba ènìyàn lábẹ́ àsíá Masses Against Electoral Fraud (MAEF) jẹ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Yewa Collective Action movement (YCAM).

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBuruji Kashamu: Èmi ṣì ni olùdíje PDP ní Ìpínlẹ̀ Ogun

Ìdí abájọ ìfẹ́hónú hàn náà ní pé wọn fẹsun màgòmágó kan ìlànà tó gbé Dapo Abiodun kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olùdíje Gomina ẹgbẹ́ APC ní ìpínlẹ̀ Ogun.

Àwọn olùfẹ̀hónú hàn gbé àkọlé orísírisi láti fí ẹ̀hónú wọn hàn pẹ̀lú àwọn akọ́lé bíí "INEC gbọdọ̀ yọ Dapo Abiodun kí àwọn agbófinró sì ṣe ìwádìí rẹ̀ ", ''A kọ Chicagogate ni ní ìpínlẹ̀ Ogun'', ''Dapo kò lé jẹ Gomina wa ní Ogun,'' ''Tinubu, Ogun kìí ṣe ìpínlẹ̀ Eko'' bẹ́ẹ̀ ní wọn wọ́ tẹ̀lé ara wọn lọ olú-ilé iṣẹ́ àjọ INEC.

Sùgbọ́n nigba ti wọn de ibẹ, wọn kọ̀ láti jẹ́ kí wọn wọlé bí gbogbo àkójọpọ gbogbo ajọ elétò ààbo ṣe kọ jálẹ̀ láti jẹ kí àwọn olùfẹ̀hónú hàn náà ó di ojú pópó.

A gbo pe àwọn olùfẹ́hònú hàn náà yarí jálẹ̀ pé àwon yòó wolé sínú ilé iṣẹ́ àjọ INEC nítori ẹ̀tó àwọn ní láti wóde ìfẹ́hónù, ṣùgbọ́n àwọn oṣìṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ náà fárígá tí wọn sí halẹ mọ wọn pé àwọn yóò yìnbọ̀n tí wọn kò bá pàdá.

Lẹ́yìn èyí ní wọn mórílé olú ilé iṣẹ́ ẹgbẹ́ APC.