Zeal Akaraiwai: Elo lẹ fẹ da le iye ẹmi eniyan?

Zeal Akaraiwai

Oríṣun àwòrán, NASA

Àkọlé àwòrán,

Zeal Akaraiwai

Lorilẹede Naijiria, perete ni irufẹ iwosan ọfẹ to wa. Nitori naa, ki ni yoo ṣẹlẹ bi o ko ba le san owo itọju ara rẹ nile iwosan?

Fun ọpọlọpọ ti ko rọwọ họri, o tumọ si pe wọn yoo daa wọn duro si ile iwosan - boya fun ọjọ melo kan tabi oṣu.

Ta ni yoo wa ran wọn lọwọ? Ninu ilu to kundun ẹsin to bayii, ọpọlọpọ alaisan ti ko r'owo san maa n reti ọna abayọ lọna ara.

Zeal Akaraiwai ko ni iyẹ bii Angẹli - o ni ọkọ ayọkẹlẹ ọlọda dudu yiyọ to rọra n dun bii ologbo.

Ọkunrin ogoji ọdun yii to jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa isuna, ko lara, o mọ lara, o jade ninu ọkọ rẹ ni ibi ti wọn n gbe ọkọ rọ si nile iwosan ijọba ti ipinlẹ Eko.

Awọn oṣiṣẹ eleto ilera kan lo fi tẹrin tọyaya ki i ku abọ o si bẹrẹ iṣe rẹ lọgan - o beere lọwọ wọn fun 'akọsilẹ orukọ'.

Lori iwe funfun balawu ni orukọ awọn alaisan tara wọn ti da to lati lọ sile wa ṣugbọn wọn ko lọ ibi kankan nitori wọn ko ri owo itọju wọn san.

Àkọlé àwòrán,

Zeal Akaraiwai

Zeal ti pade awon eniyan ti won ti fi tipatipa da duro si wọọdu fun ọsẹ mẹfa tabi mẹjọ lẹyin ti wọn ti da wọn silẹ.

Awọn ile iwosan Naijiria kọọkan ṣiṣẹ karakara lati gbe ilana kalẹ fun sisan owo diẹ diẹ ki awọn tara wọn ti ya le maa lọ ile ṣugbọn ati san owo diẹ diẹ gan nira fun awọn to n gba owo idakọ mu tabi ti ko tilẹ ni rara.

Ni wọọdu kan si kan, Zeal n fara balẹ gbọ ohun ti awọn oṣiṣẹ n sọ nipa awọn ti o lọ bẹwo.

Ni wọọdu awọn ọkunrin, awo ibole ti wọn lo ti ha lara ti ọda ti wọn fi kun ile si ti n ṣi; ogun ibusun ni wọn to sibẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn faanu atijọ n fẹ lẹlẹ awọn nọọsi si wọ ẹwu awọle lori asọ funfun wọn. Ẹwẹ, gbogbo eniyan n sa ipa wọn pẹlu gbogbo eyi.

Awọn oṣiṣẹ mu Zeal lọ si ẹba ibusun alaisan ti wọn we itan rẹ pẹlu ọpọlọpọ owu. O sun mọ ọ, o si sọrọ lohun irẹlẹ - Ki lo sẹlẹ si ọ?

Ọdọkunrin naa ni ẹnikan ti ohun ko mọ lo yin oun ni ibọn. Bawo lo ṣe wa fẹ san owo itọju rẹ? Zeal beere.

'Mo n gba adura si Ọlọrun' ni esi ti ọdọkunrin to jẹ gẹrun gẹrun fọ.

Zeal ba a sọrọ fun igba diẹ - ọkunrin naa ko beere ẹni ti Zeal jẹ bẹẹ si ni ohun naa ko sọ fun un.

Lai jẹ ki alaisan yii mọ, Zeal wadii iṣẹlẹ arakunrin yii lọdọ awọn nọọsi-aadọta le ni igba dọla ni owo ti o jẹ.

Ori rẹ baa ṣe - Zeal yoo san an. Ọkunrin naa yoo lọ ile.

Àkọlé àwòrán,

Zeal Akaraiwai

Zeal ki bikita lati beere awọn alaisan to ba ran lọwọ, ko tilẹ fẹ ki wọn sọ wi pe, 'o seun'.

Ṣugbọn ohun kan ti yoo fẹran ni pe ni ọjọ kan wọn yoo sọ itan nipa ohun - wi pe nigba ti wọn wa nile iwosan, angẹli kan wa. O san owo ti awọn jẹ, o si kuro.

"Tori naa ni mo ṣe pe akanṣe iṣẹ yii ni Iṣẹ Angẹli".

O ni, "jẹ Angẹli ti o fẹ pade".

Sisan owo itọju awọn alaisan ti ko ri i san jẹ ohun ti Zeal fi n ṣe igbagbọ tirẹ gẹgẹ bii Kristẹni.

O ni oun fẹ fi apẹrẹ lelẹ. Awọn ọrẹ ati mọlẹbi Zeal naa a maa fun un lowo fun akanṣe iṣẹ yii.

Àkọlé àwòrán,

Iwe orukọ awọn alaisan

Ni wọọdu awọn obinrin bakan naa, Zeal san owo obinrin kan to ti to ọgọta ọdun eyi to ni arun rọpa rọsẹ to lagbara ti awọn oṣiṣẹ si n fẹ ki wọn gbe e lọ si ọdọ awọn akọṣẹmọṣẹ fun itọju to peye.

O bọ ọ lọwọ, o si kuro lẹgbẹ ibusun rẹ. Ni ita, ọmọ arabinrin naa wa ba a.

Zeal ba a sọrọ itunu, o si dupẹ, o rẹrin musẹ o si pada lọ ba iya rẹ.

Àkọlé àwòrán,

Zeal Akaraiwai

Zeal kii saba ran ẹni ti iṣoro rẹ ba ga gaan lọwọ nitori pe yoo maa ru ofin ara rẹ bo ba ṣe eyi.

''Akanse iṣẹ Angẹli yii wa fun awọn to ti to lọ sile ṣugbọn ti ko ri owo san. Amọ ṣa lẹẹkọọkan, mo maa n ya bara"

Iṣe aanu rẹ nile iwosan maa n mu ọkan rẹ bajẹ. inu si maa n bi i si ijakulẹ ijọba.

''Ohun to n mu iru emi lọ sile iwosan lati lọ san owo awọn alaisan fihan pe ko si ootọ ninu iṣejọba.''

''Ko si idi ti a ko fi le ni ilana to tọ fun ilera. A ni awọn ọlọgbọn to le ronu eyi.''

Àkọlé àwòrán,

Zeal Akaraiwai

''Ọsọọsẹ ni mo n ri ipa ti aini aato to dara n ko pẹlu bi awọn eniyan ṣe n ku. Nitori naa, elo lẹ fẹ da le iye ẹmi eniyan?''