Boko Haram: Ọlọ́pàá mú afẹ̀sùnkàn olójú kan tó ti pa ju igba ènìyàn

Abdulmalik Umar

Oríṣun àwòrán, NIGERIA POLICE

Idunnu ṣubu layọ awọn ikọ IRT l'Ọjọbọ bi iroyin ṣe kan wipe ọwọ ti tẹ Abdulmalik Umar to jẹ ọkan lara awọn ogbologbo apaniyan ati ọgagun ninu Boko Haram.

Ọlọpaa ni o wa lara apaniyan ti ẹsun rẹ pọju ti ikọ IRT ti mu lati ọjọ ti wọn ti da ẹka ọlọpaa naa silẹ. Ṣugbọn ki lo jẹ ki Umar jẹ ogbologbo afẹsunkan?

Awọn ẹsun ti ọlọpaa ka sii lẹsẹ ree:

  • Umar kii ṣe ọgagun ninu Boko Haram nikan; adari ikọ adigunjale ni, bẹẹ si ni ẹgbẹgun rẹ maa n fọ ile ifowopamọ, ti o si jẹ onimọ ninu ṣiṣe ado oloro.
  • Ọlọpaa sọ pe Umar lo dari ikọ to ṣe ikọlu si Nyanya ati Kuje ni Abuja ni ọdun 2015 ninu eyi ti ado oloro ti pa eniyan mọkanlelogun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

  • Ọlọpaa ni Umar kan naa lo dari ikọ to ṣe ikọlu si orita-mẹta Galadimawa ni Abuja nibi ti wọn ti pa ọlọpaa meje.
  • Oun naa ni wọn ni o dari ikọ to pa ọlọpaa ni Lugbe ati Gwagwalada.
  • Umar ni wọn pe ni oga patapata awọn ikọ adigunjale to n ṣọṣẹ ni ipinlẹ Edo ati Ondo nibi ti wọn ti ṣe ikọlu si awọn ile ifowopamọ.
  • Oun naa ni o dari awọn ikọ to pa ogunlọgọ eniyan ni agbegbe Okene ni Ipinlẹ Kogi
  • O dari ikọ rẹ lati ṣe ikọlu si ọgba ẹwọn Kuje nibi ti awọn ọgọrun awọn ẹlẹwọn ti sa lọ. Ibi ìkọlu ọgbà ẹ̀wọn naa ni a gbọ́ pé ó ti pàdánù ojú rẹ̀ kan.

Oríṣun àwòrán, Nigeria police

Ọlọpaa ni o sa lọ nibi ti awọn ti fẹ mu ni ọsẹ mẹta sẹyin ṣugbọn ọwọ baa. Ọwọ tẹ ikọ rẹ mẹrin, ti awọn ọlọpaa si ri ibọn AK 47 mẹrin gba lọwọ wọn.

Iroyin ni ile nọọsi kan to jẹ aburo rẹ to ti n gba itọju fun ibọn to baa naa ni ọwọ ti tẹ ẹ nilu Eko.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí: