Larisa: Má jẹ́ kí ọjọ́ orí rẹ dí ẹ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ohunkóhun to wù ọ

Larisa: Má jẹ́ kí ọjọ́ orí rẹ dí ẹ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ohunkóhun to wù ọ

Abule Kalinova ni Larisa ti n ṣe iṣe olukọni ko to di ilumọọka arinrin oge.

Iṣẹ olukọ àwọn ewe ni Larisa Mikhaltsova n ṣe tẹlẹ ni eyi to ti ṣe fun odindin ogoji ọdun.

Lọdun mẹta sẹyin ni o fi iṣe olukọ dùùrù títẹ̀ sílẹ̀ lọ gba iṣe arinrin oge.

Abule Kalinova ni orilẹ-ede Ukraine ni o ti wa fun ọpọlọpọ ọdun.

Eni kan lo rii to yaa ni fọto ti o di gbajugbaja ni eyi ti ọpọlọpọ fi bẹre si ni pee si iṣẹ arinrin oge ati yiya fọto rẹ si oju awọn iwe atigbadegba.

Larisa ni oun ko jẹ ki ọjọ ori oun di oun lọwọ nigba ti asiko to lati yan iṣẹ miran laayo.

Ọmọ ọdun mẹtalelọgọta ni Larisa bẹrẹ iṣẹ arinrin oge rẹ.

O gba awọn eniyan nimọran lati dide ṣe ohunkohun to ba wu wọn lati ṣe lai naani ìdíwọ́ to ba yọju.

Gbogbo eeyan lo tẹwọgba iṣẹ Larisa tuntun, koda, ọmọ ọmọ rẹ ọkunrin lo n ṣe olootu Larisa ati aṣoju fun un.