Zura Karuhimbi dóòlà ẹ̀mi àwọn ènìyàn lọ́wọ́ ikú eléyàmẹ̀yà

Oríṣun àwòrán, Jean Pierre Bucyensenge
Zura Karuhimbi dóòlà ẹ̀mi àwọn ènìyàn lọ́wọ́ ikú eléyàmẹ̀yà
Wọn ní ọmọ burukú náà ní ọjọ́ tirẹ̀, obìnrin kan ti gbogbo ènìyàn mọ sí alágbára ti àwọn míran tilẹ̀ máa ń sọ pé àjẹ́ ní ló dóòlà ẹmí ogúnlọ́gọ̀ ènìyàn ní orílẹ̀-èdè Rwanda.
Zura Karuhimbi kò ní ohun ìjà ogun kankan láti gbèjà ara rẹ̀ lọ́wọ àwọn génde okùnrin tó kó adá àti ibọ̀n lọ́wọ́ yípo ilé rẹ̀ pé kó jọ̀wọ́ gbogbo àwọn eniyan tó kó pàmọ́ sílé.
Ǹkan tí àwọn ènìyàn mọ nipa rẹ̀ ni pé o ní agbára àìrií, èyí ló mú ìbèrù bá awọn ọkùnrín náà, èyí sì ló mú kí ó ṣeéṣé fún láti dóòlà ẹmí àwọn ènìyàn tó lé ń ọgọrùn un lọ́wọ́ àwọn tó gbé ogun abẹ́lé tó wáye ní Rwanda ní ọdún 1994.
Paul Kagametó dari ìpànìyàn náà ló di ààreẹ lọ́dún 2000.
Ó lé ní ọgọ́rún un mẹ́jọ ènìyàn láti Tutsi àti Hutu ló kú nínú ogun ẹlẹ́yàmẹ̀yà náà níbi ti Karuhimbi ti pàdánù ọmọ okùnrin àkọ́bí rẹ̀ àti ọmọ obìnrìn kan.
"Ìgbà ogùn abẹ́lé tó ṣẹlẹ̀ yìi ní mo ríi pé ọkàn ọmọ ènìyàn kún fún òkùnkùn biribiri" èyí ní ọ̀rọ̀ tó sọ fún àwọn oníròyìn lẹ́yìn ogún ọdún tí ogun náà ti pari.
Oríṣun àwòrán, AFP
Awọn Hutu àti Hutsi lásìkò ogun 1994
Karuhimbi kú jẹ́jẹ́ nínú ìlé rẹ̀ lọ́jọ́ kẹtàdínlógún, oṣù yìí ní abúlé rẹ̀ Musamo, kò sí ẹní to rí àrídájú ọjọ́ orí rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bíi ǹkan tí o máa n sọ yóò ti lé ni ẹni ọgọ́rùn un ọdún, sùgbọ́n ìwé àkọsílẹ̀ ní ẹni ọmọ ọdún mẹ́tàléláàdọ́rùn ni.
Larisa: Má jẹ́ kí ọjọ́ orí rẹ dí ẹ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ohunkóhun to wù ọ
Ipenija ojú kò di Ademola lọ́wọ́ láti kẹkọọ gboye
Wòlíì Àrólé sọ àsọtẹ́lẹ̀ s'áyé BBC ní London