Christmas: Buhari rọ àwọn Krìsìtẹ́nì láti fìfẹ́ hàn sí ara wọn

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ikini ku ọdun

Aarẹ Muhammadu Buhari rọ awọn Onigbagbọ lati maa fifẹ bawọn eeyan lo bi wọn ti n ṣe ayẹyẹ ọdun Keresimesi.

Aarẹ sọrọ yii ninu ikini ọdun to fi ranṣẹ si awọn ọmọ lẹyin Kristi.

Aarẹ ni bi wọn ti n yọ, ti wọn si n fun ara wọn lẹbun ti wọn lọ sile ara wọn, ki wọn maa gbagbe pe awọn kan ko lanfani lati wa pẹlu ẹbi wọn lasiko yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Èpo ọwọn, sunkere-fakere ọkọ àti àwọn olósà jẹ́ ipenija lójú pópó

Aarẹ ni o ṣe pataki fun awọn onigbagbọ lati ranti awọn ọmọ ogun ti wọn n ja fitafita lati ri wi pe alaafia jọba kaakiri orilẹede Naijiria.

Aarẹ Buhari ni awọn arugbo, awọn alaisan ati awọn akanda ẹda lo yẹ ki a fifẹ han si lasiko ọdun ibi Jesu yii.

Buhari ni asiko yii ṣe pataki lati ranti pe ẹgbẹgbẹrun ọdun sẹyin ni ibi Jesu waye ni Bethlehem Judea eyi to tumọ si ireti, igbala, aforiji ati alaafia.

Àkọlé fídíò,

Ipenija ojú kò di Ademola lọ́wọ́ láti kẹkọọ gboye

Bakan naa, oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP Atiku Abubakar nini iṣẹ ikini ku ọdun tirẹ rọ awọn ọmọ Naijiria lati fi ifẹ han si awọn eeyan.

Atiku tun rọ awọn eeyan lati bara wọn laja lakoko ọdun Keresimesi yii.

Àkọlé fídíò,

Wòlíì Àrólé sọ àsọtẹ́lẹ̀ s'áyé BBC ní London