The seed: Àwa sì wá láti mú ẹ̀bùn fún Ọba tí a bí lónìí!

The seed: Àwa sì wá láti mú ẹ̀bùn fún Ọba tí a bí lónìí!

Asiko keresi jẹ asiko láti ranti alaini, opó, alaisan atawọn mii lawujọ.

Damilọla Brown. ọkan lara àwọn ọmọ ẹgbẹ akọrin akapẹ́là náà ṣalaye kikun fun BBC Yoruba lori irufẹ ọdun ti keresimesi jẹ ni agbaye.

Ogbeni Aliyu to jẹ oludari ẹgbẹ akorin naa ki oriki orin akapẹla ni kikun.

Bakan naa lo gba awọn eniyan ni imọran lati tẹra mọ iṣẹkiṣẹ ti eeyan ba yàn laayo ki o le ṣe aṣeyọri ninu ẹ.

Ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu kejila, ọdọọdun ni gbogbo onigbagbọ lagbaye fi maa n sami ọdun keresimesi ti wọn fi n ranti ọjọ ibi Jesu Kristi, olugbala araye.

Opọ lo gba pe o jẹ asiko lati fi ifẹ han si ara, ọrẹ, ojulumọ atawọn to wa ni ipò aini ki inu wọn naa lè dun lasiko ọdun.

Àwọn ọmọ lẹyin Jesu Kristi gbagbọ pe ọjọ ibi Jesu yii lo mu igbala kikun wa si aye ti iku ko fi lagbara lori awọn mọ́.