Yuletide: Saraki, Fayose ní kí àwọn ọmọ Nàìjíríà wo àwòkọ́ṣe Jésù

Bukola Saraki àti Ayo Fayose fàdúrà ọdún Kérésì ráńṣẹ́

Oríṣun àwòrán, @Bukolasaraki, @GovAyoFayose

Àkọlé àwòrán,

Bukola Saraki àti Ayo Fayose fàdúrà ọdún Kérésì ráńṣẹ́

Lórí irú àṣàyàn ọ̀rọ̀ tí Bukola Saraki ati Peter Ayodele Fayoṣe fi ṣe ìkíni ọdún Kérésì, àwọn ọmọ Nàìjíríà ti ń fún un ní onírúurú ìtumọ̀.

Lójú òpó Twitter, ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Nàìjíríà Bukola Saraki kí gbogbo ọmọ Nàìjíríà kú ọdún Kérésì àti ọdún tuntun.

Ó ní "mo fẹ́ fun 'pè sí àwọn Krìstẹ́nì àtàwọn ọmọ Nàìjíríà lápapọ̀ láti fi àwọn ìṣé rere Krístì ẹni to fi ara rẹ̀ rúbọ fún ìgbàlà ọmọnìyàn".

Lọ́gán tí àwọn ọmọ Nàìjíríà rí ìkíni yìí ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ síí fèsì.

Àkọlé fídíò,

'Oníbárà ló pọ̀ jù nínú àwọn òṣèrè'

Chantel Adanna ní "Oníwàásù gidi ni ABS ooo. Pásítọ̀ Bukola Saraki!!! Àwọn ìdí pàtàkì kan wà tí mo fi fẹ́ràn yín, olórí tí kò fi ti ẹlẹ́yàmẹ̀yà ṣe. Ẹ ṣeun tí ẹ kí wa kú ọdún Kérésì"

Babatunde Adebajo da Saraki lohun pé, " Ẹ kú ọdún Kérésì o ẹ̀wẹ̀, mo lérò wí pé ìwọ àti àwọn olóṣèlú àti ìwọ fúnra rẹ ló yẹ kí o sọ ọ̀rọ̀ yìí sí! Àwọn ọmọ Nàìjíríà ti farajìn fún yín tó ju kí ẹ máa rẹ́ wa jẹ lọ.

Tunbosun ní, "Nígbà tí ìdìbò bá ń sún mọ́ ni wọ́n máa ń rán wa létí láti wo àwòkọ́ṣe Krístì. Bí wọ́n bá ń pín owó gọbọi gọbọi pẹ̀lú ìwà ọ̀bàyéjẹ́, wọ́n á gbàgbé àwòkọ́ṣe Jésù, kódà bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ò tíì r'óúnjẹ jẹ. Ẹ kú dún lẹ́ẹ̀kan síi o Bukky.‏

Àkọlé fídíò,

Asisat Oshoala: ìbẹ̀rẹ̀ mi kò rọrùn rárá nínú eré bọ́ọ̀lù

Bákan náà, bí wọ́n ṣe ń dá Saraki lóhùn ni Gómìnà àná ti ìpínlẹ̀ Ekiti, Peter Ayodele Fayoṣe náà ń gba èsì sí ìkíni tirẹ̀.

Ayo Fayose fi ìkíni tirẹ̀ èyí tí ṣàlàyé ojútùú sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro tó ń dojú kọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Nínú ọ̀rọ̀ ìkíni rẹ̀tí akọ̀wé rẹ̀ Ọ̀gbẹ́ni Idowu Adelusi fi síta, Fayose ní ṣíṣe ìgbọ́ran sí àwọn ìkọ́ni Jésù Krístì ní ọ̀nà àbáyọ sí àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ àwọn orílẹ̀èdè.

Ẹ̀wẹ̀ lójú òpó Twitter rẹ̀, àdúrà ni Fayoṣe kẹnu bọ̀ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà pé "ìbí Jésù Krístì yóò gbà wá àti orílẹ̀èdè wa là kúrò nínú ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀, ìṣẹ́ àti ìjìyà".

Àkọlé fídíò,

The seed: Àwa sì wá láti mú ẹ̀bùn fún Ọba tí a bí lónìí

Adekoya Ayodele náà kí Fayose padà pé, "Kú ọdún Kérésì o Apata tí àwọn aláìlẹ́mìí nínú ń bẹ̀rù.

Abayomi Oluwagbemiga naa fèsì pé, Lóòtọ́, Ọlọ́run yóò tú wa sílẹ̀ nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àti ìpò tó ba ni nínú jẹ́ èyí tí PDP ti kó orílẹ̀èdè yìí sí.

Àkọlé fídíò,

Èpo ọwọn, sunkere-fakere ọkọ àti àwọn olósà jẹ́ ipenija lójú pópó

Adebayo Joseph Olufemi ni Fayose, "má gbàgbé ìpè rẹ láti dí Pásítọ̀ o. Èyí ni ààò rẹ kóo tó fi ipò sílẹ̀. Ẹ kú ọdún Kérésì àti Ọdún tuntun.

Àkọlé fídíò,

Oludije ipò Gómìnà labẹ asia PDP ní Oyo sọrọ nípa Ladoja