2018 films: Sinimá ju sinimá lọ táwọn ọmọ Naijiria gbádùn

Oríṣun àwòrán, @kemi Adetula
Ṣọla Ṣobọwale di iya àwọn ọmọ to lé
Eré ju eré lọ, ìran ju ìran lọ lawọn sinimá to jade lọdun 2018.
Oriṣiríṣii nkan lo ṣelẹ lágbo oṣere ni Naijiria lọdun 2018 nibi ti ọpọlọpọ fiimu agbelewo ati ti sinima ti jade loniruuru.
Ko si bi ọ̀bẹ́ ṣe pọ̀ to lọjọ iku erin, awọn ọ̀bẹ kan ṣi maa jẹ ajitanna wo ni ọrọ awọn sinima to jade ni 2018 jẹ.
Diẹ lara awọn to ta julọ ni a ṣakojọpọ rẹ yii lai nii fi ṣe pe bayii ni wọn ṣe dùn tó.
'Mí ò ya wèrè, mí ò burú, ọ̀nà àtijẹ là ń wá'
Black Panther
Fiimu yii jẹ akọkọ fun ọpọlọpọ idiyele ni gbogbo agbaye.
Oun ni ikẹsan ninu gbogbo fiimu agbaye ti awọn eeyan wo julọ ni eyi ti wọn gbe kiri sinima kaakiri agbaye ti wọn si pa owo pupọ lori.
Marvel Universe lo gbe e sita ti olu ẹda itan rẹ jẹ eniyan dudu ti ibudo itan si jẹ afihan ilẹ Adulawọ ati ilẹ Gẹẹsi.
Black Panther ni fiimu to ta julọ to jẹ pe alawọ dudu lo dari ẹ,
Ìsọ̀ oníwe ìròyìn àtàwọn tó ń kà a lọ́fẹ̀ẹ́
King of Boys
Ọmọ Yoruba to n gbé ogo Naijiria ga ninu eré oniṣe lasiko yii, Kemi Adetiba lo dari sinima King of Boys.
O ti pa to igba miliọnu naira laarin ọsẹ meje pere ti fiimu naa jade.
Eré yii ni fiimu Naijiria to n ta julọ nipo kẹrin, ohun naa tun ni sinima to n ta julọ fun igba pipẹ ti awọn ero iworan si n woo julọ.
'Ìyá Tíṣà lòdì sí kí n mutí, fagbó tàbí sìgá'
Avengers: Infinity War
Sinima yii mi igboro tìtì lagbaye debi pé wọn gbee de ipinlẹ̀ Eko ni Naijiria.
Fiimu yii ni akọkọ fiimu ologun ti yoo pa ju biliọnu meji dọla owo ilẹ Amẹrika lagbaye.
Avengers yii naa tun ni fiimu to ta julọ lagbaye lọdun 2018.
'Isẹ́ Tíátà tí mò ń se ti tó mi jẹun'
Asisat Oshoala: ìbẹ̀rẹ̀ mi kò rọrùn rárá nínú eré bọ́ọ̀lù
Sylvia
Fiimu yii ni ọpọ gba pe o jẹ ọkan lara àwọn fiimu Naijiria to dara julọ lọdun 2018.
Ohun gan ni Nollywood yan fọsẹ kan ni Paris gẹgẹ bii fiimu wọn.
Zainab Balogun paapaa gba yiyan fun ami ẹyẹ ELOY lataari ipa to kó ninu fiimu naa.
Chief Daddy
Gbogbo aye ti mọ Ebony Life pe wọn maa n gbe fiimu jade lopin ọdun ni.
Bi wọn ṣe gbe The Wedding party apa kinni ati apa keji jade lasiko naa ni wọn ṣe gbe e jade.
Opọlọpọ oṣere Nollywood Naijiria lo kopa ninu Chief Daddy. Fiimu naa lo gab ipo keji ninu iṣide fiimu lọdun 2018.
'Èmi ò kí ń lu ìyàwó mi'
Aquaman
Lati igba ti Justice League ti jade lawọn eeyan ti n poungbẹ fun fiimu omiran bẹẹ.
Fiimu yii naa yombo akọni ẹda itan. Lati igba to ti jade ni awọn eeyan ti n gabdun rẹ ti wọn ti n foju sọna fun apa keji.
Lara and The Beat
Seyi Shay jẹoṣere Nollywood tuntun nibi to ti kopa olu ẹda itan ninu fiimu onijo-lorin yii.
Vector ayarasọrọ gbajugbaja oju tawọn ọmọ Naijiria n gba fun lasiko yii ni wọn jọ kopa ninu eré onijo-lorin ọhun.
Biola Alabi lolootu ere naa nigba ti Tosin Coker dari ẹ.
The seed: Àwa sì wá láti mú ẹ̀bùn fún Ọba tí a bí lónìí
Moms at War
Funke Akindele, iya ibeji tuntun Funke Akindele ti di ìyábejì àti Omoni Oboli ni wọn jọ jẹ olu ẹda itan inu fiimu yii.
Eré naa jẹ eré apanilẹrin to ta daada nile iworan sinima kaakiri Naijiria. Eucharia Anunobi naa kopa ninu eré naa.
Larisa: Má jẹ́ kí ọjọ́ orí rẹ dí ẹ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ohunkóhun to wù ọ
New Moni
Tọpe Ọshin lo ṣe fiimu yii sita ninu eyi ti Jemima Osunde ti kopa olu ẹda itan rẹ akọkọ.
Wọn ṣe fiimu yii papọ pẹlu Inkblot ati Filmone.
Njẹ ọ mọ̀ pé mímí afẹ́fẹ́ tí kò dára lè fa àìsàn?
Lion Heart
Genevive Nanji, ogbontarigi oṣere binrin Nollywood lo dari ere naa ni eyi to fihan pe o le ṣe iṣẹ aludari ere fun igba akọkọ.
Aye tun sọrọ fiimu naa sii nigba ti wọn ni Netfilx ti ra ẹ̀tọ́ fiimu naa. Wọn ti n gbee kaakiri awọn ile iworan sinima ni Naijiria.
Iroyin nii ọdun to m bọ ni fiimu naa a wọ Netflix.