Ayẹyẹ Ọdún Anlugbua ti ìlú Kuta, Ọṣun
Àgbò tó wà láàyè, ajá àti iyán pẹ̀lú ọbẹ̀ẹ́yọ̀ wà lára àwọn ǹkan ètùtù l'ójúbọ Anlugbua.

Oríṣun àwòrán, Olowu of Kuta
Ayẹyẹ Ọdún Anlugbua ti ìlú Kuta
Oríṣun àwòrán, Olowu of Kuta
Àwọn ará ìlú Kuta, ìpínlẹ̀ Ọṣun gẹ́gẹ́ bí tọmọdé tàgbà ṣe máa ń ju ọwọ̀ níbi ayẹyẹ náà.
Oríṣun àwòrán, Olowu of Kuta
Ìdọ̀bálẹ̀ gbalaja ni àwọn ará ìlú fi ń kí Ọba
Oríṣun àwòrán, Olowu of Kuta
Bí ìwọ̀n kìlómítà mẹ́ta ni ojúbọ náà fi jìnà sí ìgboro
Oríṣun àwòrán, Olowu of Kuta
Ibí yìí ni wọ́n bo òrìṣà Anlugbua mọ́lẹ̀ sí tó sì ti di ojúbọ tí gbogbo ará ìlú ti ń wúùre
Oríṣun àwòrán, Olowu of Kuta
Olowu ti Kuta, Ọba Oba Adekunle Oyelude Makama ló darí àwọn aráàlú lọ sínú aginjù tí ojúbọ náà wà
Oríṣun àwòrán, Olowu of Kuta
Ọba tó fi mọ́ àwọn olóyè àti gbogbo ará ìlú máa ń ṣe ìwọ́de yí ìlú wọn ká
Oríṣun àwòrán, Olowu of Kuta
Oba Adekunle Oyelude Makama pẹ̀lú gbogbo ìlú lọ bọ baba ńla rẹ̀, Akindele tí wọ́n mọ̀ sí Anlugbua
Oríṣun àwòrán, Olowu of Kuta
Inú igbó kìji kìji ni wọ́n ti máa ń lọ bọ baba ńla wọn
Oríṣun àwòrán, Olowu of Kuta
Àwọn àgbààgbà ìlú a máa fi ijó tiwọn náà dára yá