DR Congo: Àtúndì ìbò yóò wáyé lọ́dún tó mbọ̀

Àwọn aráàlú kọlu ìbùdó ìtọjú Ebola ní DR Congo

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Àwọn aráàlú kọlu ìbùdó ìtọjú Ebola ní DR Congo

Ifẹhonu han n waye lorilẹede Democratic Republic of Congo lẹyin ifasẹyin to ba eto idibo aarẹ lawọn apa ibi kọọkan lorilẹede naa.

Ajọ eleto idibo lo foju ganni itujade arun Ebola. Awọn apa ibi ti ikọlu yii ti waye jẹ gbungbun awọn ọmọ ẹgbẹ alatako to si ni ju oludibo ẹgbẹrun kan to forukọ silẹ.

Ẹtọ lati dibo jẹ ohun ti wọn ko fi ṣere rara. Ni orilẹede DR Congo, o jẹ ohun to bofin mu ṣugbọn ti ajọ eleto idibo ba ro o wi pe awọn ko le ṣe eto idibo lawọn ibi kọọkan nitori iṣẹlẹ ara ọtọ, ofin naa ti wọn lẹyin lati ṣe idibo lawọn ibi ti wọn ba ti lee ṣe.

Akọṣẹmọṣẹ nipa ofin ọmọ ilẹ Congo, Tresor Makunya sọ pe ofin to ni ṣe pẹlu eto idibo ko ye yekeyeke ohun ti wọn yoo ṣe. iwoye tirẹ ni wi pe Ile ẹjọ ofin nikan, kii ṣe ajọ eleto idibo ni o lee gbe gbedeke le ẹtọ awn eniyan lati dibo.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Ìbùdó ìtọjú Ebola ní DR Congo

Ẹwẹ, ajọ eleto idibo ni awọn yoo ṣe eto idibo lawọn agbegbe mẹrin ọhun ninu oṣu kẹta - ṣugbọn ninu akọsilẹ kan naa, ajọ eleto idibo ni awọn yoo kede esi aṣekagba idibo aarẹ lọjọ kẹẹdogun oṣu kinni ti wọn yoo si bura wọle fun aarẹ lọjọ ikejidinlogun oṣu kinni.

Ile iṣẹ BBC ti bere fun alaye kikun lọwọ ajọ eleto idibo lori bi wọn yoo ṣe ko ibo ti wọn ba di loṣu kẹta sinu eyi to ku lẹyin ti wọn ba ti baba ṣe gbogbo ohun ti wọn sọ ṣaaju yii --- Ni bayii, wọn ko tii ri idahun si awọn ibeere yii.

Jacques Ndjoli to jẹ ọjọgbọn onimọ ofin eto idibo to tun jẹ sẹnetọ lati ẹgbẹ alatako kan gbagbọ pe ọ̀rọ̀ ti ko lẹsẹ nlẹ ni ki wọn tilẹ gbiyanju lati gbe èsì náà lọ sile ẹjọ.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Àwọn aráàlú kọlu ìbùdó ìtọjú Ebola ní DR Congo

"Ka ma tan ara wa, kii tilẹ i ṣe ile ẹjọ olofin la ni. Ile ẹjọ oṣelu ni eyi to n gbe lẹyin ẹnikan atawọn ọrẹ rẹ. Ile ẹjọ yii ko tii figba kan ri lodi si ifẹ àwọn to wa nijọba. Mi o tii ri ibi ti ara ilu tabi ẹgb alatako ti gbe ẹjọ kan lọ ile ẹj to si jẹ pe awo Ọgbẹni Kabila ni awọn adajọ.

Àwọn ẹkun mẹrẹẹrin nibi ti wọn ti sun ibo siwaju jẹ ibi ti wọn ri gẹgẹ ibi ti awọn ẹgbẹ alatako ti fẹsẹ mulẹ daadaa, nitorinaa ọpọ ri igbesẹ lati dena idibo yii gẹgẹ bi ọwọ oṣelu.