Aishat Lola: Kò s'óhun tí mo ṣe tó tẹ́ ìyá mi lọ́rùn

Aishat Lola

Oríṣun àwòrán, @Aishatlola

Àkọlé àwòrán,

Aishat Lola

Aishat Ọmọlọla to jẹ akẹkọọ ipele kẹta ni ile iwe giga fasiti Ahmadu Bello gba ẹmi ara rẹ lọjọru ọj kẹtadinlogun oṣu yii.

Iroyin to tẹ wa leti sọ pe ninu ile rẹ ni agbebe Samaru nipinlẹ Kaduna ni wọn ti ba oku rẹ pẹlu lẹta to kọ silẹ to fi dagbere fun awọn ọrẹ rẹ.

Nigba ti BBC Yoruba ba ile iṣẹ Ọlọpaa sọ̀rọ̀, wọn ni lootọ ni Aisha mu majele. Lẹyin naa, wọn gbe e digba digba lọ sile iwosan ko to di pe o gbẹmi mi.

Loju opo Twitter ọrẹ rẹ, @Mer_yherm jẹ ko di mimọ pe Aishat n ba oun sọrọ lọwọ lori Watsap lori eyi to ti fi lẹta idagbere to kọ kalẹ sọwọ si i ko to gbe majele jẹ.

Lati igba naa ni awọn ọmọ Naijiria ti n fi ọrọ ikẹdun ati erongba wọn lori igbesẹ yii ranṣẹ.

Ninu lẹta rẹ, o pari rẹ pe ki wọn sin ohun ni kete ti wọn ba ti rii pe oun ku.