Dino Melaye: Mò ń bọ wá yojú sí yin lágọ́ọ̀ ọlọ́pàá

Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, @dinoofficial

Àkọlé àwòrán,

Dino Melaye: Mò ń bọ wá yojú sí yin lágọ́ọ̀ ọlọ́pàá

Sẹnatọ Dino Melaye tí fẹ̀sì sí àtẹ̀jáde àjọ ọlọ́pàá, ó no òun kìí ṣe ọdaràn nítori náà láìpẹ́ òun yóò yọju sí àgọ́ ọlọ́pàá.

Dino Melaye sọ èyí di mímọ̀ lọ́nìí ọjọ́ satide pé bí àwọn ọlọ́pàá ṣe yabo ilé oun kò ní ìtumọ̀ rárá.

Lọ́jọ́ jimọ ní àwọn ọlọ́pàá bí ogun yabo ilé Dino Melaye láti mu.

Mí ò mọ ǹkan ti wọn ń lépa mi fun. mí kìí ṣe ọdàran. E ò lè pami lẹ́nu mọ. Ẹ ò lé fi tipa gbárùkù tí ẹni ti mí o nífẹ̀ẹ́ si ni dandan'' àwọn ǹkan ti dino sọ rèé lóri ẹ̀rọ ibanisọ̀rọ̀

Dandan ní kí a mú Dino sí àhámọ́ wa-Ọlọ́pàá

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti jáde pé àwọn ò ní kúrò nílé Sẹ́natọ Dino Melaye títí yóò fi fojú hàn fún àwọn láti mú.

Wọn ní Dino lọ́wọ́ sí àwọn tó pa ọlọ́pàá kan.

Agbẹnusọ àjọ ọlọ́pàá Jimoh Moshood nínú àtẹ̀jáde kan tó fọ́wọ́ sí sàlàyé pé àwọn ti kọ̀wé sí àkọ̀wé ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin pé kí Dino Melaye fójú kàn ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá tó wà ní ìpínlẹ̀ Kogi láti sọ tẹnu rẹ̀ sùgbọn ó fààké kọ́rí kò yojú.

Àtẹ̀jáde ọ̀hún fí kún pé sẹ́nátọ Dino Melaye àti àwọn ìsògbè rẹ̀ jọ fí ọwasowọ́pọ̀ láti yìnbọn pa Sajẹnti Danjuma Saliu tó wà lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Kogi nínú oṣù keje ọdún 2018.

Nínú ọ̀sẹ̀ yìí ní Dino Melaye ké gbànjarè pé ọgá àgbà ọlọ́pàá fẹ mú òun láti gún òun lábẹ́rẹ́ ikú

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wá ni ǹkan tí àwọn sọ fún Dino Melaye lásìkò náà ní pé tó bá mọ p'\e òun ti ṣẹ̀ sófin kò wá jẹ́wọ́