New Year Message 2019: Ọ̀rọ̀ ìdìbò kìí tìpátìkúùkù

Buhari ṣe ìkíni ọdún Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Buhari ṣe ìkíni ọdún

Ààrẹ Muhammadu ní kí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ó máà fòyà nítorí, ìdìbò ọdún 2019 yóò lọ ní ìrọwọrọsẹ̀ bí ọ̀pọ̀ àwọn olùdíje ààrẹ ti tọ́wọ́ bọ̀wé àláfíà lẹ́yìn ìdìbò 2019.

Ọ̀rọ̀ ìdánilójú ló wà nínú ìkíní tí ààrẹ Buhari fi ṣọwọ́ sí àwọn ọmọ Nàijíríà fún ọdún tuntun 2019.

Nínú ọ̀rọ̀ ìkíni yìí bákan náà Buhari tún ṣe ipolongo nínú rẹ̀, "mo lérò pé ẹ ó dìbò fún wa lọ́dún 2019 lati tún lo ọdún mẹ́rin mìíràn nílé ìjọba bí ẹ ṣe gbárùkù tì wá lọ́dún 2015."

'Ọdún 2019 pẹ̀lú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó kó lọ́wọ́ dé'

Nàìjíríà á bí ọmọ 25, 685 lọjọ́ kínni, oṣù kinni, ọdún 2019.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNew year message: Buhari, Jonathan, Atiku, kí àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà

Olúkúlùkù ọmọ Nàìjíríà ló sọ èrò ọkàn wọn lóri ọ̀rọ̀ ààrẹ fún ìkíni ọdún tuntun

"Ọmọ Nàíjíríà ń fẹ́ àláfíà, ètò àbò, ìlọsíwájú, àjọṣepọ̀ nínú ètò ìdàgbàsóke amúludùn àti orílẹ̀-èdè tí yóò ma jẹ́ ìwúrí láàrin àwọn orílẹ̀èdè''

Àkọlé àwòrán New Year Message 2019: Ọ̀rọ̀ ìdìbò kìí tìpátìkúùkù
Àkọlé àwòrán Se ìkíni ọdún ní Buhari ń se ni tàbí ìpolongo ìdìbò.

Buhari ní kò sí ǹkan ìwúrí kankan tí a fí ń sìrú ìlú ju ifẹ̀ orilẹ̀-èdè yìí lọ, ṣíṣe iṣẹ́ ilú láì fi ìmọ̀ tara ẹni síi, ó fi dá ará ìlú lójú pé itẹ̀síwáju yóò máa wà ní sísẹ̀-ń-tèlé ní Nàíjíríà. Awọn onímọ tara ẹni níkan ní kò tii rí àwọn ayípadà ńlá ti ìjọba tí ṣe láti ọdún 2015.

Bákan náà, Buhari tún pè fún gbogbo ará ìlú láti túbọ̀ fí ara wọn jìn láti mú ìran Nàìjíàríà ṣẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIkorodu Bois: Ko si ẹni ti a kò lè sín jẹ!