Boko Haram: Iléeṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà ń wá Dókítà Brimah tó ń fi ìkówójọ 'owó oúnjẹ ọmọ ogun lu jìbìtì

Awọn ologun n gba ounjẹ Image copyright Nigeria Army
Àkọlé àwòrán Ileeṣẹ ologun ni ko si idi fun ikowojọ fun awọn ọmọ ogun Naijiria nitori wọn ko sunkun ebi fún ẹnikẹni

Ileeṣẹ ọmọogun Naijiria n wa arakunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Dokita Perry Brimah bayii lori ẹsun pe o n fi ọna eru ṣe ikowojọ lorukọ ileeṣẹ ọmọogun Naijiria to n koju ikọ agbebọn Boko Haram.

Dokita Brimah yii ti o n gbe loke okun ni wọn ni o nlo orukọ "Global Campaign To Provide Food For Nigerian Soldiers Fighting Boko Haram". Lati fi gba owo lọwọ awọn eeyan pẹlu erongba pe awọn smọogun to n koju Boko haram ni yoo ko fun.

Buhari ní ìdìbò 2019 kìí ṣe tikú-tìyè

Iya Rainbow, Jide Kosoko, Ọga Bello, yóò polongo Buhari fún 2019

Dino Melaye ní ọlọ́pàá ti fẹ́ wó ilẹ̀kùn ilé mi lulẹ̀ báyìí o

Ninu atẹjade kan, alukoro ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ lorilẹede Naijiria, Sani Kukasheka Usman fi sita, awọn ololufẹ orilẹede Naijiria ati ileeṣẹ ọmọogun rẹ ni arakunrin naa ti fi jibiti gba owo lọwọ wọn bayii.

Ileeṣẹ ọmọogun ni ko si iya ohun ti o njẹ awọn ọmọogun Naijiria ti o n ja fun aabo ilẹ yi ati pe ko si ọmọogun Naijiria to sunkun ebi lọ ba ẹnikẹni ki a to sọ pe beere fun ikowojọ fun owo ounjẹ.

Wọn wa rọ gbogbo awọn to ba ri arakunrin naa lati fi to awọn agbofinrin nilẹ Naijiria tabi oke okun leti.