Ìwà ipá nínú ìdílé máa ń bí ìgè àti àdùbí ni tó lè já sí ikú- Agbejoro Abiola Abiade

Ìwà ipá nínú ìdílé máa ń bí ìgè àti àdùbí ni tó lè já sí ikú- Agbejoro Abiola Abiade

Ọpọ ẹ̀mí ọkọ àti aya ló sọnù ní Naijiria lọdun 2018 látàrí ìwà ipá nínú ìdílé.

Amofin Abiade Abiola bá BBC Yorùbá sọrọ lori ìrírí rẹ̀ ninu igbeyawo pẹlu imọran fawọn ènìyàn pé nitootọ ifẹ dara ṣugbọn ko gbọdọ mu iku dani.

Kini Agbejoro Abiola tun salaye sii?

Ọpọlọpọ iku lo ṣẹlẹ laarin lọkọ laya Lọdun 2018 ni Naijiria ti awọn ololufẹ gun ara wọn pa sinu ilé ni eyi ti ofin ṣi le ya wọn sọtọ ki wọn ṣi wa laye.

Amofin Abiade ṣalaye igbesẹ to yẹ ni gbigbe ni kikun fun ikọsilẹ labẹ ofin Naijiria.

O sọ pataki igbani-niyanju lọdọ Pasitọ, Imaam ati amofin agba fun lọkọ laya ki wọn le jọ wo ọna abayọ si ija ojoojumọ wọn.

Lẹyin ti ile ẹjọ ba rii pe igbani-nimọran yii ko bi èso to yẹ ni wọn a ni ki lọkọlaya to n ja yii yẹra funra wọn fun igba diẹ, o pẹ tan, fun ọdun mẹta.

Lẹyin yiyẹra funra ẹni fun ọdun mẹta yii ni lọkọ laya ṣẹṣẹ le beere fun ikọsilẹ ni eyi ti agbara wa lọwọ Adajọ lati ṣe tabi ko tun fun wọn ni igbesẹ alaafia miran.

Amofin Abiade gba awọn eniyan Naijiria nimọran pe kaka ti ẹmi a fi maa sọnu lọdun tuntun, ko buru ki onikaluku ni imọ lori igbesẹ to yẹ ni gbigbe labẹ ofin Naijiria.

O ni o sàn ki lọkọlaya yago funra wọn fun igba diẹ ju ki wọn maa gun ara wọn pa sinu ilé lọ.