Ìjàmbá ọkọ̀ ojú'rin tó ṣubú wáyé ní Agége l'Eko

Ọkọ oju'rin to subu Image copyright @rrslagos767

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ijamba ọkọ oju'rin kan waye ni Agege nipinlẹ Eko.

Ijamba naa lo waye ni oju ọna irin ni agbegbe Mangoro Ashade, lagbọ wipe ẹsẹ ọkọ oju'rin naa yẹ kuro loju ọna rẹ, to si fi ẹgbẹ lelẹ lasiko to wa lori ìrìn.

Agbegbe Iju ni ọkọ naa ti gbera, to si n lọ si Ebute-Mẹtaa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌjàmbá ọkọ̀ ojú'rin tó ṣubú wáyé ní Agége l'Eko

A gbọ wi pe ni bii aago meje owurọ ni iṣẹlẹ naa waye, ti wọn si ti gbe awọn to farapa lọ sileewosan bayii.

Iṣẹlẹ naa si ti mu ki sunkẹrẹ, fakẹrẹ ọkọ o gbode ni awọn agbegbe to o yi ibi to ti waye ka. Ṣugbọn awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa, LASEMA, LRT, LRU PARAMEDICS, LRU FIRE, LASAMBUS, FRSC, RRS, LASTMA wa nikalẹ lati mu gbogbo nkan pada bọ sipo.

Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí sọnù sínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú'rin lásìkò tí wọ́n n wòran ọdún

Eeyan 18 ku ni marosẹ Ibadan si Eko

Iṣẹlẹ naa waye lẹyin ọjọ mẹta ti ajọ to n mojuto igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko, LASTMA fi ikede kan sita loju opo Twitter rẹ pe awọn irin kan ti yẹ̀ kuro ni aaye wọn ni oju'rin ọhun, to si n fẹ atunṣe ni agbegbe Mangoro Ashade yii kan na.

Igba akọkọ kọ niyii ti iru ijamba bẹ ẹ waye nipinlẹ Eko. Ọkan waye l'oṣu Keje ọdun 2018 lasiko ti ọkọ oju'rin kan kọlu ọkọ elero mẹrinla kan ni agbegbe Agege-Pen Cinema. Bakan naa ni ọkọ oju'rin gba ọmọbinrin kan to jẹ agunbanirọ agbegbe Ikẹja l'oṣu Kẹta ọdun 2018 bakan naa.

Related Topics